Ọmọọba Jamiu Ademoye
Ọba Sulaimon Adeshina Raji-Ashade , Oniba- Ẹkun tilu Iba, nipinlẹ Eko,ti fi idunnu ẹ han si gbogbo awon alejo to wa ba a ṣe ajọyọ ikomọ tuntun ti iyawo ẹ, Olori Muslimot Sulaimon Raji-Ashade bi fun un.
Oniwaasi agbaaye nni, Sheik Muyideen Ajani Bello, to waasu lọjọ naa sọ nipa awọn ohun idagbasoke ti ọba naa ti mu ba ilu ọhun lakooko to ti gori itẹ awọn baba rẹ.
Alaaji Muyideen sọ bi Ọlọrun ṣe ma n dara fun ẹda nipa ọmọ bibi. Bẹẹ lo wa ba Oniba dupẹ fun ti ajọyọ ọmọ tuntun naa pẹlu adura pe ki Ọlọrun fun un ni ẹmi gungun ati alaafia lati fi tọju ọmọ naa.
Bakan naa lo tun ṣe adura fun lya ọmo yii ati ilu lba, ipinlẹ Eko ati Orileede Naijiria lapapọ.
Orukọ ti wọn sọ ọmọ naa ni Muh. Qazim Abiṣade, Adebọwale, Akanni, Adedimẹta, Desire, Adeyinka, ( Ati opolopo oruko abiso) Sulaimon Adeshina Raji-Ashade
Oludari eto ijoko, ilu mooka oniroyin nni, AbdulFatai AbdulGafar naa mẹnuba onirunru awọn igbega to ti de ba ilu naa nipa eto ilera , Gbọngan ẹrọ ayara bi aṣa ati awọn eeyan lawujọ ti wọn ti wa si ilu yii nipasẹ Oniba- Ẹkun.
Lara awon ọba alade ti wọn wa nibẹ ni Ọba Moruf Ojoola ( Ojon ti Ejigbo) ,Ọba Kabiru ( Osolo ti ilu lsolo) ,Ọba Hamed Orelope-Laka ( Ẹlẹgbẹda) , Ọba Akibu ( Orisunbare) , Ọba Oloto, Onijankin,
Bẹẹ tun ni Ọba Saheed ( Idi Oke ) Onigboko, Ọba Elekunpa , ati bẹẹbẹẹ lọ. Bakan naa lawan baalẹ ilu naa ko gbẹyin lara wọn ni Baba Ọba ilu Iba, Ọnarebu Oloye Suarau, Baalẹ ijẹ dodo, Oloye Jẹlili ati mii-ii
No comments:
Post a Comment