Ajọ Ṣẹgunfunmi ati ileewosan OOU fawọn to ni aisan jẹjẹrẹ lẹbun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 17 October 2023

Ajọ Ṣẹgunfunmi ati ileewosan OOU fawọn to ni aisan jẹjẹrẹ lẹbun


Lati ma ṣe jẹ ki awọn to ni aisan kan ro ara wọn pin pe opin ti de ba wọn tabi ko si ọna abayọ mọ fawọn ajọ kan to n ṣatilẹyin fawọn to ni iru aisan bẹẹ iyẹn Ṣẹgunfunmi Cancer Support Foundation pẹlu ifọwọsowọpọ ileewosan ẹkọṣẹ yunifasiti  Ọlabisi Ọnabanjọ,  Ṣagamu, ti  fawọn aadọta to n ba aisan yii ni ẹbun

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igbesẹ ọhun jẹ ayajọ itaniji aisan jẹjẹrẹ ti oṣu yii, to waye nijọba ibilẹ Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

 

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni gbọngan Lekan Ogunyẹmi, to wa ni ọgba ileewosan naa, Dokita Olubunmi Fatungaṣe to jẹ ọga agba nileewosan naa, o kọkọ gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lori bo ṣe n pese awọn eroja to yẹ fun wọn paapaa ibi ti wọn ti maa ṣayẹwo fawọn ti jẹjẹrẹ ba a finra, ki wọn si le tete tọju ẹ.

O waa gba awọn obinrin nimọran lati lọ maa ṣe ayẹwo ọyan wọn loorekoore, ki wọn si tun ri i pe wọn tete gba ileewosan lọ ni kete ti wọn ba ti ri pe wọn ni aisan naa. O ni o san ju ki wọn pa a mọra titi ti yoo fi gba ẹmi wọn lojiji.

 

 

Dokita naa tun ṣalaye pe’’ " Bi awọn obinrin ṣe maa n ku lori aisan jẹjẹrẹ yii ti pọju. Bi wọn ba tete ri ti wọn si bẹrẹ itọju ẹ le jẹ ki iku naa dinku laarin wọn.  Pẹlu bi eto aabo ṣe mẹhẹ, ati bi igbe aye ṣe dinku, awọn eeyan ni lati ṣamojuto ara wọn nipa eto ilera, pataki ni eleyi jẹ fun wọn.

 

Ninu ọrọ ti Dokita Adeleke Adekọya, ti ẹka iṣẹ abẹ, o sọ pe o ṣe pataki lati da ẹgbẹ kan silẹ ti yoo faye gba awọn to ni aisan jẹjẹrẹ laaye lati sọ ero ọkan wọn, ki wọn si ri iranwọ loju ẹsẹ, o ni o san ju ki wọn wa iranwọ wọn lọ sibomii-ii. Bẹẹ lo tun gba awọn ẹbi atawọn ọrẹ ti wọn ba ni ẹni to ni aisan nimọran lati fi ifẹ han fun wọn.

 

Nigba ti wọn fi ẹmi imoore wọn han, Arabinrin Grace James ati Alaaja Adefunkẹ Aina, dupẹ lọwọ awọn to ṣonigbọwọ eto ọhun fun ẹbun nla ti wọn gbe fun wọn yii, bẹẹ lo ni awọn yoo maa ṣayẹwo ara wọn loorekoore.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages