.
Gẹgẹ bi iwadi wa iṣẹlẹ to waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii fihan pe gbogbo ete ni igbakeji ẹ n lo lati ta epo si ala ẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe loootọ ni igbimọ alakoso ere bọọlu naa se ipade ọfiisi wọn ni Surulere amọ ko sigba kankan ti wọn mẹnuba a pe wọn da alaga wọn duro.
Iroyin to tẹ wa lọwọ.fi ye wa pe nibi ipade ọhun ni Liameed ti dabaa pe ki wọn da alaga naa duro amọ ọmọ ẹgbẹ meje yooku tako aba naa nitori wọn ni wọn ko ri idi pataki lati gbe igbesẹ naa.
Wọn lo ti gbimọ yii silẹ daadaa nipa pipe awon oniroyin kan si kọrọ, to si pe wọn wọle si ipade oniroyin ti wọn ko pe wọn si, nigba ti erongba lati yọ alaga wọn ko bọ si fun un
Ọkan lara igbimọ to ba oniroyin wa sọrọ sọ pe igbakeji alaga ọhun lo yẹ ko jiya lori awọn iwa ti ko bofinmu to hu nipa ṣiṣe adehun pẹlu awọn onigbọwọ laijẹ kawọn igbimọ gbọ
.
No comments:
Post a Comment