Gbajumo olorin fuji nni, Saheed Osupa, ni yoo sere nibi ayeye odun Aje Olokun tawon OPC New Era maa n se lodoodun ti yoo waye lojo Aje, ojo kokanlelogun si ojo Isegun, ojo kejilelogun, osu yii, ni Debojo Beach, Eleko, Ibeju Lekki, nipinle Eko.
Gee bi atejade ti Ogbeni Alexander Adesina, fi sita loruko Aare egbe naa, Oloye Rasak Arogundade Balogun, lo ti so pe awon ti gbaradi fun ayeye odun yii,eyi to so pe o maa larinrin.
Lati aaro, ojo Aje, Monde, ojo kokanlelogun, lawon omo egbe OPC New Era yoo ti maa de si ibudo naa, nitori awon etutu ti won yoo se gege bi ise won lodoodun.
Nigba ti asekagba yoo waye lojo Issgun, nigba ti Yeye Olokun yoo saaju awon omo egbe New Era loo sadura, ti ayeye iweje-wemu yoo si bere, nibe ni Saheed Osupa yoo ti sere fun won.
Lara awon ti won n reti nibe ni Oba Saliu Babatunde Saliu,Oloworo tiluu Oworo, ti yoo je Baba oba alade ti ojo naa,Oba Ajibola Talabi Odugbesan,Onidebojo tiluu Debojo ni olugbalejo pataki.
Awon yooku tun ni Oloye Ifagbemi Osungbemi Omitunmise, to je Iya oosa Ipakoda Ikorodu ni mama ojo naa nigba ti Oloye Olabosipo Olaseinde,Iyalaje oodua gbogbogboo naa ko ni gbeyin.
No comments:
Post a Comment