Bi ki i ba se ise akinkanju tawon eso asobode ipinle Ogun n se, ti won ko si foju awon onifayawo bale, o ku die ki won ko ota ibon lorisirisi wolu, amo sa owo palanba won segi.
Gege bi Bamidele Makinde, to je oga agba fun ajo asobode iyen kositoomu se WI lakooko to bawon oniroyin soro, o ni ota ibon to le ni egberun kan ati igba le ni marundinlogoji lawon ri gba ninu apo nla kan ti won ko gbogbo re si.
O so pe lojo Eti Furaide, ojo kokanla, osu kejo ni won ta ileese asobode lolobo pe awon kan n gbidanwo lati ko eru ofin wolu ati pe orileede olominira Benin, ni won ti n ko o bo.
O ni loju ese lawon ko ti foro naa fale rara, tawon si ko awon osise won loo sibe lati maa so agbegbe naa.
Makinde tun fi kun ninu oro e pe nigba ti yoo fi di oru ojo naa lawon ri moto Toyota Kamri marun-un.
Awon moto naa pelu nomba won ni
4TIBG22KIWU312145, 4TIXK1263NU1082, JM2GD14H201568566, JMZGF14F201173029 ati JMZGF14P20141862 ..
Inu igbo kan lona Tobolo lati fee wonu orileede Benin legbe Ijoun nijoba ibile
Yewa North, lo so pe awon ti ri moto to kun fun apo iresi.
O salaye siwaju pe, "Bawon dereba fayawo naa se gburo wa ni won gba inu Igbo naa sa lo,nitori ki a ma ba a mu won".
"Ninu ayewo wa la ti ri awon nnkan to ya wa lenu ninu okan lara moto naa, ota ibon lorisirisi to le ni egberun kan,ati igba le marundinlogoji, lo kun bamubamu ninu apo naa. Olorun nikan lo mo ijamba ti won ko ba fi se, ka ni won raye ko o wole"
Makinde waa so pe ara ona lati maa samojuto aabo lawon enu aala orileede wa ni eleyii pelu ileri pe awon yoo tubo maa sagbara won lati ri i pe abo to peye yii wa.
O so pe igbelewon iye owo eru ofin tawon ri gba je milionu metadinlogun,egberun lona egbeta le mejidinlogun ati aadojo din marun--un naira.
Oga agba naa waa pari oro e pe gbogbo nnkan tawon gba yii lawon ti ko pamo, Titi ti igbese to ye yoo fi waye ati pe iwadii won si n tesiwaju lati mo awon to wa nidii Kiko ota ibon yii wolu.
No comments:
Post a Comment