Alaaji Lamidi Apapa, alaga lapapo fun egbe oselu Labour lorileede yii ti so pe ko si wahala kankan ninu egbe naa mo ati pe bi ilosiwaju yoo tubo se ba egbe naa lo je won logun.
Okunrin naa soro yii lakooko ti won se ifilole awon alaga fidihe,ti eka ipinle Eko, to waye lose to koja.
Ayeye ti won se yii ni o fopin si gbogbo wahala to n waye lori ipo alaga, to ti n waye ninu egbe naa latigba ti won ti pari Ibo gbogbogboo.
Onarebu Adesoyin Olumide ni alaga igbimo fidihe fegbe oselu ipinle Eko nigba ti Basorun Omotayo Anjorin, Olanrewaju Olanrewaju Akanbi Ibrahim ati Arabinrin Alaka si je igbakeji e.
Lara awon to tele Alaaji Lamidi Apapa wa sibi ayeye naa ni Abayomi Arabanbi, akowe olupolongo egbe naa lapapo
Ninu oro Onarebu Moshood Adegoke Salvador, lo ti so pe idi pataki ti won fi yan awon oloye egbe tuntun lati apapo de ipinle ni lati je ki ooto joba, nitori akoko tawon kan n dari won si Igbo ti koja
Abayomi Arabanbi so ninu tie pe nnkan tawon fe ni pe leyin tawon ba ti gba Idajo, ki won ki awon Ku oriire.
Bee lo kesi awon olopaa pe enikeni to ba pe ara e ni Oloye egbe leyin awon ti won Yan yii ki won gbe won.
Nigba toun naa soro lojo naa, Alaaji Basiru Lamidi Apapa so pe Ko si nnkan to je pe awon pada seyin mo, Abure alaga egbe won tele ti lo yoo si foju winna ofin ijoba laipe Lori awon esun ti won fi kan an
O so pe igba die lo ku tawon omo orileede yii yoo fi mo eni to n paro laaarin oun ati Obi pelu Abure.
Bee lo so pe gbogbo Iro ti Obi n pa pe oun ko ri oun ri ni yoo han sita, o waa ro awon omo egbe lati fowosowopo pelu alaga won tuntun yii.
Ninu oro alaga fidihe, o dupe fun anfaani ti won fi fun oun yii ati pe oun yoo ri pe ipada si rere yoo de ba won nipinle Eko.
No comments:
Post a Comment