Irọ ni wọn pa o, mi o mọ nipa wahala ọrọ ilẹ Adunbun l’Ewekoro- Alaaji Owoẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 9 August 2023

Irọ ni wọn pa o, mi o mọ nipa wahala ọrọ ilẹ Adunbun l’Ewekoro- Alaaji OwoẹyẹAlaaji Mutairu Owoẹyẹ, ọkan lara awọn gbajumọ awọn to n ta ilẹ fi ṣowo, ti ke gbajare sita pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn kan sọ pe ileeṣẹ oun wa lara awọn to n da wahala silẹ ni abule kan ti wọn pe ni Adunbun, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun.

 

 

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita lo ti sọ pe bi igba ti wọn fẹẹ maa ba oun lorukọ jẹ, ni oun ka ọrọ naa si, ati pe awọn to wa ninu mọdaru ni wọn ṣiṣẹ yii. Bẹẹ lo tun fi aidunuu ẹ han lori bi wọn ki ọrọ ti Olu Itori, Ọba Abdul fatai Akamọ, bọ wahala ọhun, to ni ko yẹ ki wọn maa parọ mọ ori ade.

 

Gẹgẹ bi atẹjade ọhun ṣe lọ,’ Mo gbọ nipa awọn irọ ati ahesọ kan ti wọn kọ nipa mi lori ẹrọ ayelujara, lori ikọlu to n waye ni abule Abundun, mo fẹẹ ki awọn araalu mọ pe ọna mii in ti wọn fẹẹ fi ba mi lorukọ jẹ ni eleyii nitori  mi o mọ nipa ẹ rara’’

 

‘’ Bẹẹ ni mo si tun le fọwọ sọya ko si ọkan ninu awọn oṣiṣẹ mi ti wọn lọọ da wahala silẹ ni awọn agbegbe, nitori gbogbo wọn ni wọn mọ nipa ofin, ti wọn si n pa a mọ, a o lọwọ ninu ija kankan o’’

 

 

" Ko si si nnkan mii-in bi ko ṣe pe ọna ati ba mi lorukọ jẹ ni wọn n wa, lati bi ọsẹ meji ni ara mi ko ti ya, ti mo n gba itọju,bẹẹ ni ko si ọna ti mo le gba ran awọn eeyan lọọ da wahala silẹ’’

No comments:

Post a Comment

Pages