Miliọnu mẹtala naira ni a pa wọle ninu oṣu keje ọdun yii- Oga asobode ipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 9 August 2023

Miliọnu mẹtala naira ni a pa wọle ninu oṣu keje ọdun yii- Oga asobode ipinle Ogun



 

 

Ileeṣẹ aṣọbode tipinlẹ Ogun, ti sọ pe miliọnu lọna ọgọrun-un le mẹfa naira ni iye awọn ẹru tawọn gba lọwọ awọn fayawọ nigba tawọn si pa milọnu mẹtala naira wọle ninu oṣu keje to pari yii.

 

Ọga agba ileeṣẹ ọhun, Bamidele Makinde, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fọwọ si eyi ti Hammed Bukoye Oloyede, to jẹ agbẹnusọ  gbe jade lorukọ ọga naa. O sọ pe apo irẹsi ti gbogbo ẹ jẹ ẹgbẹrun meji ati ọgọfa din meje, 2,113 ati taya aloku ti iye ẹ jẹ Okòó-lé irínwó-din mẹrin,lawọn tun gba ninu oṣu naa.

 

Bẹẹ lo tun sọ pe ninu akọsilẹ fun oṣu to kọja yii lawọn tun gba awọn mọto mọkanlelogun, ti wọn jẹ Tokunbọ, àgbá epo pẹtiroolu oni lita ẹgbẹrun mejidinlogun-din -aadọta atawọn  nnkan mi, eyi to jẹ ki gbogbo ẹ jẹ miliọnu lọna ọgọrun-un le mẹfa naira.

 

Makinde tun ṣalaye siwaju pe pẹlu gbogbo agbekalẹ tawọn ṣe iye tawọn pa wọle ninu oṣu naa ni milọnu mẹtala, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le ni aadọrin ati igba naira.

 

Bakan naa ni ọkunrin yii tun lo anfaani ọhun lati fi dupẹ lọwọ ọga agba wọn pata lorileede yii,  Bashir Adewale Adeniyi, atawọn eeyan ẹ fun abẹwo ti wọn ṣe wa si ipinlẹ Ogun, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, eyi to ni o tun jẹ ki iṣẹ wọn tun gbooro si pẹlu ileri pe awọn yoo rii pe ilakaka wọn tun tẹsiwaju.

 

Makinde tun waa fi akoko yii gboriyin fawọn ọmọọṣẹ fun bi wọn ṣe jẹwọ akikanju ninu awọn iṣẹ ti wọn  n ṣe, to ni o n mu aṣeyọri ba gbogbo wọn pọ. Bẹẹ lo wa gba wọn niyanju lati ma ṣe rẹwẹsi, ki wọn si gba a gẹgẹ bi iṣẹ ti wọn yan laayo.

 

O waa pari ọrọ ẹ nipa didupẹ lọwọ awọn ẹka alaabo yooku fun ifọwọsowọpọ wọn, atawọn ọba alaye to wa ni agbegbe Idi iroko paapaa bi wọn ṣe gba ọga agba pata wọn lalejo ni afin Oniko Ikolaje ati Onipokia ti Ipokia.

 


No comments:

Post a Comment

Pages