Ẹ jẹ ka gbaruku ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ninu ijọba ẹ- Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 13 July 2023

Ẹ jẹ ka gbaruku ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ninu ijọba ẹ- Salvador



Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador , to ti figba kan jẹ aṣoju-ṣofin niluu Abujam to tun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Eko, ti rọ gbogbo awọn ọmọ ilẹ kaarọ-o-jiire lati ṣatilẹyin nla fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, to jẹ aarẹ lorileede yii, ko le tubọ ṣe aṣeyọri nla ninu ijọba ẹ.

Ọkunrin naa sọrọ lakooko to n ba ẹgbẹ awọn oniroyin Yoruba, iyẹn League of Yoruba Media Practioner, LYMP, fọrọ-jo-mi-toro- ọrọ, nile ẹ lana an. O sọ pe lati ọjọ ti wọn ti da Naijiria silẹ, lọdun 1960, ti wọn ti gba ominira, akọkọ ti oun maa maa ri ọmọ Yoruba to jẹ aarẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni oun ko le pe Shonẹkan ni aarẹ,nitori fidihẹ ni, ko si ni agbara kankan,  nitori ko si nnkan to le da ṣe, ko si to ija ọmọ Yoruba gbe.O ni bi ẹ ba ri ẹni to to ija wa gbe, oun gbọdọ sọ ni, ati pe  oun ati Tinubu, ko saa si ninu ẹgbẹ kan naa mọ ,amọ ti wọn ba n sọ ẹni to to o gbe Aarẹ yii ni.

Salvador  tun fikun ọrọ ẹ pe Tinubu yii lo le ba iran Yoruba kọ awọn iya ọjọ iwaju, to si ti n ba wọn kọ ọ bayii.

Ọkunrin naa tun sọ pe, ‘’ Mo ranti lakooko ti ipolongo idibo aarẹ n lọ lọwọ, ẹnikan beere pe awọn eto wo ni Tinubu ni lọwọ, to fẹẹ gbe kalẹ,  esi to fi da onitọhun loun ni pe, oun ko le sọ o, toun ba lọ sọ, ki wọn lọ pa oun’’.

‘’Idi ree, kudiẹkudiẹ ti baba wa Awolọw ṣe, eyi Oloye MKO Abiọla ṣe, oun ko le ṣe e,itumọ ẹ niyẹn, kin ni kudiẹkudiẹ ọhun,wọn lọ leri, wọn lọ leka pe bawọn ba dori aga,awọn a ṣe awọn nnkan bayii,awọn to  maa ni lara, ko jẹ ki wọn de bẹ’’.

‘’Lakooko naa,o ṣẹnu ẹ dakẹ, inu igbo ni ẹyẹ n gbe, o gbe ẹnu ẹ dakẹ, o jẹ ki agbara tẹ oun lọwọ, o waa bẹrẹ iṣẹ ọhun,ẹ o rii pe laaarin ọsẹ kan to de bẹ, gbogbo ọna ole, jibiti tawọn tibi n ṣe, o kọkọ muu kuro, o maa nira, ko si nnkan to dara ti ki i nira, lati ọjọ ti wọn ti da ilẹ Yoruba silẹ, ti wọn ti da Naijiria silẹ, ọmọ ilẹ Yoruba kankan ko jẹ ọga agba patapata fun aṣobode ri. Ko pe ọjọ mẹta to debẹ lo yii pada, ẹ woo, bi wọn ṣe fawọn onibode wa sẹyin lati ọdun yii, ko pe ọjọ mẹta, oun naa waa ṣe pe nnkan ti ẹ ṣe fun wa loun naa yoo da pada’’.

‘’Yoruba lo wa n ko si gbogbo ẹ, ẹ ẹ ri pe ka to wi, ka to jokoo, o ti yọ ọga banki agba, o ti fi ọmọ kaarọ o-jiire si.Ati bẹẹbẹẹ lọ.Ẹ ma reti tọrọ, ẹ ma reti kọbọ, ẹ ranti awọn ọmọ yin lọjọ iwaju.Ti ẹ ba ri ẹni to n ṣe eleyii, ẹ gbaruku ti, nitori nnkan to n ṣe yii, fun awọn ọmọ yin lọjọ iwaju ni o’’.

O waa sọ pe bi ọrọ ba ri bayii onikaluku wa lo maa ni ipa to maa ko, fun ilọsiwaju ilẹ Yoruba, ki ẹ ma jẹ ki ipa yin ko gbẹyin o. Nipa ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, to jẹ ọmọ Yoruba, toun naa ti ṣe aarẹ ri, Salvador sọ pe wọn kan muu wa ṣe pẹlu adehun to wa laarin wọn ni.

O ni ‘’Ọbasanjọ ko ni ẹkùn tabi agbegbe ,bẹẹ  ni ko ni ẹka kankan, ṣugbọn ẹni to ni awọn nnkan wọnyii to ti n ja fun iran ilẹ Yoruba, oun ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, akọkọ ni to yanranti. Awọn ko ṣe jẹ ki MKO Abiọla jẹ aarẹ, ti wọn wa lọ mu eeyan wa lati inu tubu, ẹni ti wọn lọ mu wa, wọn ti ni adehun pẹlu ẹ. Gbogbo nnkan tawọn ara oke ọya ba n fẹ, ni yoo maa ṣe,ki i ṣe nnkan ti awa ba n fẹ, nitori ẹ ni ẹ ṣe n ri ti,Baba wa Ọbasanjọ, ṣe n sọ lọjọ naa pe oun yoo  yan ipo si gbogbo ipinlẹ, awa lo tun fiya jẹ ninu ẹ’’.

‘’Gbogbo ipo awọn ara oke ọya lo n fun, wọn ko ni agbara, wọn kan jẹ aarẹ ni. Nitori awọn ara oke ọya ni wọn fi sibẹ.

Salvador  waa sọ pe ki a si fi ẹgbẹ oṣelu silẹ, lakooko yii, nitori bi oun ba sọ fun yin pe ẹgun gun yin ni ẹsẹ, ọ lọ ki ẹ yọ,, ko ma baa ta yin, to ba ta yin, a toro si yin lara, a si ṣe yin leṣe,ewo ni ti ẹgbẹ oṣelu ninu ọrọ ilọsiwaju ilu.

‘’Kin ni ẹ fẹẹ fi wọn ṣe, emi ko jisoro ẹgbẹ oṣelu kankan,igbesẹ lasan ni lati fi de ibikibi ti ẹ fẹẹ de. Awọn agba bọ wọn ni, agba ki i wa lọja ki ori ọmọ tuntun wọ, ori ọmọ tuntun kọ lo wa fẹẹ wọ yii, ori awọn agba gan-an ni, a maa mura lati ba ara wa sọ ootọ ọrọ,ọmọ ẹni ki i ṣe idi bẹbẹrẹ ki a fi ilẹkẹ sidii ọmọ ẹlomii-in. Oun ni nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre’’ Salvador lo  sọ bẹẹ.

O ni, ‘’ Oun lo mu Baba Faṣoranti ṣe nnkan to n ṣe, Baba Adebanjọ oun sọ  pe oun ba Tinubu ja, o ni a fi ti wọn ba ṣe atunto, ṣebi oun naa ni wọn n ṣe yii. Gbogbo wa la jọ wa ipade apero ni 2014, emi naa wa nibẹ, gbogbo nnkan taa to pe ti wọn ba ṣe ilu yii a di rẹpẹtẹ, oun ni wọn n ṣe yii.’’

‘’Adura ni ki ẹ maa fi ran Aarẹ yin tuntun yii lọwọ, nitori bawọn ara oke ọya ko ba pa a, wọn yoo dero ẹyin patapata, nitori bo ṣe n ba lọ yii, ọrọ atunto yii lo tun ti gbe siwaju wọn yii, boya ẹ ti ri gbọ, ahesọ ọrọ to n jade, bi ẹ ba si pe bẹẹ ẹ o ri ootọ, gbogbo ipinlẹ to wa ni ẹkun mẹfẹẹfa lorileede yiim ki ọkọọkan wọn ni ipinlẹ meje, ki aparo kan ma le ga ju ọkan lọ’’.

‘’Wọn tun ti la silẹ pe, bi a ba pin ni ipinlẹ meje,meje,ipinlẹ kọọkọn gbọdọ maa pa biliọnu dọla, eyi ti ko ba ti le pa to bẹẹ, wọn yoo kede ẹ bi ipinlẹ pajawiri, ẹ sẹsẹ fẹẹ mura, k onikaluku lọ ṣe alumọni ti Ọlọrun fi kẹ wọn, ki wọn maa jokoo ti owo baba l’ Abuja’’.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages