Akoba nla lawọn fayawọ mu ba idagbasoke ọrọ aje wa lorileede yii- Ọga agba kọsitọọmu Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 11 July 2023

Akoba nla lawọn fayawọ mu ba idagbasoke ọrọ aje wa lorileede yii- Ọga agba kọsitọọmu Ogun



Ọga agba fawọn kọsitọọmu nipinlẹ Ogun, Bamidele Makinde, ti sọ pe loootọ lawọn ko foju awọn fayawọ balẹ lori gbigbogun ti wọn lori bi wọn ṣe n ko ẹru ofin wọle, sibẹ, awọn yoo tun maa rọ wọn lati jawọ ninu iṣẹ ọhun, nitori akoba nla ni wọn mu ba idagbasoke orileede wa.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ṣe ipade pẹlu awọn oniroyin nipa irinju iṣẹ wọn laarin oṣu mẹfa akọkọ ninu ọdun yii, eyi to waye ni ọfiisi wọn, to wa ni Idi-Iroko,nipinlẹ Ogun.Bẹẹ lo tun rọ awọn onikarakata lati ṣiṣẹ pọ fun ifọkanbalẹ lori iṣẹ ti wọn ba n ṣe.

O sọ pe inu oun dun lati mẹnuba awọn aṣeyọri tileeṣẹ ọhun laarin oṣu mẹfa akọkọ, nipa owo to wọle, fayawọ ati karakata to waye.O ṣafikun ọrọ ẹ pe owo wọle laarin akoko naa jẹ miliọnu mẹtalelaadọrun, ẹgbẹrun ọkanlenirinwo ati aadoje naira ( N93,301,130.000), eyi to sọ pe o tun gbẹnusoke ta a ba ni ka fi ṣafiwe tọdun to kọja, tiyẹn jẹ miliọnu mọkandinlọgbọn,ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrun le ogoji ati Aadoje Naira (N29,940,146.50), ti ida ẹ jẹ ọọdunrun le mẹwaa.

Makinde tun ṣalaye pe laarin oṣu mẹfa ti wọn sọ yii awọn ko foju awọn fayawọ balẹ, tawọn si gba oriṣiriṣi awọn ẹru ofin bii ọọdunrun ati mejilaadọrun(392). Lara ẹ ni aloku taya ẹgbẹrun marun-un ati mejilelaadọta(5048) Ọọdunrunlelaadọrun aṣọ aloku, mọto mọkanllọgọta,bọọsi gungun marun-un, epo tanka onilita  173,975,  oogun oloro, irẹsi atawọn nnkan mii-in.

 O lawọn ṣe awọn aṣeyọri yii nipa itẹsiwaju awọn alaadani , itọpinpin kaakiri ipinlẹ yii ati ikoraẹni nijanu ati ifọkansin awọn oṣiṣẹ wọn. Bẹẹ lo ni awọn ikọ alaabo yooku naa tun ran awọn lọwọ fawọn aṣeyọri yii.

O tun sọ pe’’ Ṣe ẹ ranti nini ipade oniroyin ta a ṣe kọja, mo mẹnuba ipinlẹ pe ileeṣẹ wa labẹ ẹgbẹ awọn iyawo wa iyẹn Customs Officers’ Wives Association (COWA), ṣefilọlẹ ileewe alakọbẹrẹ ati nọsiiri, inu mi dun lati sọ fun pe iṣẹ ti fẹẹ pari lori ẹ’’

Bakan naa lo wa lo akoko naa lati fi ki ọga wọn agba pata tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ya B A Adeniyi, fun ipo to wa bayii, o sọ pe laifi ọrọ sabẹ ahọn sọ ọkunrin koju oṣuwọn ati pe igbagbọ wọn ni pe yoo ṣe aṣeyọri nidii ẹ.


No comments:

Post a Comment

Pages