Idi ti mo se pe Gomina Dapo Abiodun ni Gbatueyo-Segun Sowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 29 June 2023

Idi ti mo se pe Gomina Dapo Abiodun ni Gbatueyo-Segun Sowumi



Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ọkan lara ẹgbẹ agba oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe loootọ loun fẹran Gomina Dapọ Abiọdun, ti oun fura oun ko le sọ pato idi to fi ri bẹ amọ bo ṣe n ṣe ijọba ẹ jẹ eyi to ba ni lọkanjẹ, nitori ki i gba amọran.

 

Ọkunrin to ti figba kan dije fun ipo gomina nibi ibo abẹle to waye labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ipinlẹ Ogun, sọrọ ọhun lakooko to n bawọn ẹgbẹ akọroyin Yoruba lorileede Naijiria ti a mọ si League of Yoruba Media Practitioners, fọrọ-jo mi-toro-ọrọ laipẹ yii.

 

O fikun ọrọ ẹ pe titi di akoko yii loun ṣi maa n beere lọwọ ara oun, idi toun fi fẹran Gomina ọhun, toun gan-an funra oun ko ri esi gidi kan sọ.

 

Ọtunba naa sọ pe, “Mo fẹran Dapọ Abiọdun gidi, emi fura mi ko mọ idi ti mo ṣe fẹran rẹ. Ki i ṣe pe a jọ wa ninu ẹgbẹ kan naa, a ko si ni ohunkohun lati ṣe papọ, ṣugbọn mo kan fẹran rẹ ni. Mo ro o titi lati mọ idi ti mo ṣe fẹran Dapọ Abiọdun, ṣugbọn mi o ri idahun sii.

 

“Bi ọrọ ipinlẹ Ogun ṣe maa n ṣe mi ni pe mo maa n fẹ ko jẹ pe awa la ma maa gbegba oroke nibi gbogbo, idi ree ti mo fi maa n sọrọ nibi ti kudiẹ-kudiẹ ma ti n waye.

 

“Nigba ti Dapọ Abiọdun bẹrẹ iṣakoso lọdun 2019, ko tete yan awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ fun oṣu mẹfa, mo wa bẹrẹ sii pe e si akiyesi. Ohun mi le gan-an nigba yẹn. Igba naa ni mo sọ Dapọ Abiọdun lorukọ, ti mo si pe e ni ‘Gbatuẹyọ’.

 

“Lẹyin eyi ni gomina ko awọn ọmọ rẹ sita, ti wọn si bẹrẹ sii sọ oriṣiriṣi si mi, ṣugbọn ko dun mi, nitori pe ko tu irun kankan lara mi. Lẹyin naa la pade nibi kan, ti gomina si da omi tutu si mi lara, ibẹ lati sọrọ, ti a si ṣere. Latigba naa ni mo ti maa n ṣagbeyẹwo ọrọ daadaa ki n too gbe kalẹ, paapaa to ba ti jẹ nipa ọrọ ijọba Dapọ Abiọdun. Mo rii pe ifẹ yẹn wa nibẹ.

 

“Lasiko eto idibo to kọja yii, Gomina Dapọ Abiọdun ti mu mi kuro ni PDP tan, diẹ lo ku, nitori pe mi o gba tikẹẹti, ṣugbọn mo ti pẹ ninu iṣẹ PDP ju ki ẹnikan ṣẹṣẹ wa maa pe mi lati maa bọ ninu ẹgbẹ miran lọ, idi ree ti mi o fi dahun nigba yẹn.

 

“Nigba ti idibo tan, a wa bẹrẹ sii gbọ oriṣiriṣi wi pe wahala ti ṣẹlẹ, wọn ti da ibo ru, wọn ni wọn ti lu wọn, wọn ti gun wọn, wọn ti ṣa wọn. Ṣugbọn nigba ti mo ti bẹrẹ sii ri awọn kan layika ijọba Dapọ Abiọdun ni mo ti bẹrẹ sii pe e si akiyesi. Mo kọ apilẹkọ kan, ṣugbọn ti mi o pada gbe jade nitori ifẹ.

 

“Nnkan ti mo kọ sibẹ ni pe ‘Gomina Dapọ Abiọdun fura si awọon ijakumọ ti wọn ti n so mọ ọn, ti wọn n ba oju ijọba ijẹta jẹ, ti wọn si n ba iṣẹ ẹni ẹlẹni jẹ’, eyi ti oloyinbo pe ni ‘Dapọ Abiodun, becareful of the familian demons that created all the reputational damage of the government of Daniel.’

 

“Mo ti kọ apilẹkọ yẹn nitori pe mo ti mọ ibi ti ọrọ naa maa pada ja si, ṣugbọn mi o gbe e jade. A dibo, eto idibo kọja. Gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ, a maa sọ pe a ko gba, idi ree ti a fi wa nile ẹjọ. Ọnarebu Ladi Adebutu sọ pe wọn fẹẹ pa oun, o ti salọ si London, bẹẹ naa ni Akinlade to jẹ igbakeji ti wa ni London, ko wa sẹnikẹni nile.

 

“Abẹokuta ni ẹjọ naa ti ba mi, mo si rii pe awọn ọmọ wa, wa nile, idi ree ti mo fi lọ si ile-ẹjọ lọjọ naa. Igba ti mo debẹ, afi bi ẹfun ati eedi, nigba ti mo debẹ. Gbogbo awọn to wa nibẹ ni mo ki, igba ti mo fẹẹ wọle, wọn sọ pe wọn ti tilẹkun, ẹnikẹni ko le wọle, mo si yipada loju ẹsẹ.

 

“Afi b’awọn janduku ti wọn n ko kaakiri ṣe wa ba mi niyẹn, ti wọn si bẹrẹ lọjọ naa, Ọlọrun lo yọ mi lọjọ yẹn. Idi ti mo fi binu diẹ niyẹn. Nigba ti iru nnkan bayii ṣẹlẹ lọdun, bi gbogbo ilu ṣe gbe ẹnu dakẹ, ti wọn ṣebi ẹni pe awọn ko mọ nnkan to ṣẹlẹ niyẹn.

 

“Nitori mo nigbagbọ pe a ko le tori oṣelu, ka sọ ilu di jakujaku. Gbogbo ero ọkan mi ni pe Dapọ Abiọdun yoo bẹ mi nitori pe a ti mọ ara wa, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ. Eyi la ṣi n fa lọwọ ti wọn tun da ti Daniel si.

 

 

 

Bakan naa lo tun sọ pe ọpọ igba loun ti kilọ fun awọn ti Gomina Dapọ Abiọdun ko mọra ninu iṣakoso rẹ, nitori pe pupọ ninu wọn ti ba gomina tẹlẹri, Ọtunba Gbenga Daniẹl ṣiṣẹ papọ, toun si mọ ipa ti onikaluku wọn ko.

 

Ṣugbọn oun wa rii gẹgẹ bi ẹni ti ko ṣetan lati tẹle amọran fun awọn idi pataki to ye e.

 

“O ni bi wọn ṣe n ṣe idibo abẹle tẹlẹ, Daniel gba tikẹẹti ninu APC, o si polongo ibo. Wọn dibo akọkọ, boya nitori Tinubu t’awọn eeyan fẹẹ dibo fun, ibo yẹn lọ daadaa. O wa di ọsẹ meji lẹyin ẹ, ibi ti ẹgbẹ APC ti wọle daadaa, o wa di ibi ti wọn ko tiẹ ti jawe olubori rara nigba idibo gomina, to si wa di wahala.

 

“Gomina Dapọ Abiọdun padanu ni wọọdu, ijọba ibilẹ, ẹkun ijọba apapọ ati bẹẹbẹẹlọ. To ba wa ri bẹẹ, ko yẹ ki ẹ wa di gbogbo ẹbi naa ru ẹnikan ṣoṣo. O yẹ ki wọn ro o wi pe ṣe Ọtunba Gbenga Daniel nikan lo wa ninu ẹgbẹ wọn ni adugbo yẹn ni. Ibẹ ṣaa ni akọwe ijọba ti wa, ibẹ naa si l’awọn alẹnulọrọ ti wa, koda ti awọn alaga ijọba ibilẹ tun wa nibẹ pẹlu, ki lo wa de to jẹ pe ariwo Daniel ni wọn n pa kaakiri.

 

“Ṣe agbara Daniel naa lo wa pọ to bẹẹ, to jẹ pe o le bori ibo lọjọ Satide, ko si tun padanu ẹ lọjọ Sannde? O yẹ ki ẹ mọ pe irọ ni. Aanu Gomina Dapọ Abiọdun lo n ṣe mi, nitori pe bi wọn ba maa ba orukọ awọn kan jẹ laaarin ilu, iru awọn nnkan wọnyi ni wọn n ṣe lati fi ba orukọ ẹni yẹn jẹ.

 

“Ṣe ohun to kan bayii ni pe ki wọn lọ maa lu awọn to jẹ ọmọ ẹyin Daniel, ṣe bi wọn ṣe n ṣe ijọba niyẹn. Gbenga

daniel ko ba ẹnikẹni ja, nitori pe wọn ko fẹ wahala.”

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages