Aṣofin to n ṣoju ẹkun Ila Oorun ipinlẹ Ogun (Ogun East) nile igbimọ aṣofin l'Abuja, Ọtunba Gbenga Daniel, ti sọ pe ko si nnkan tawọn kan le maa sọ si oun lakooko yii, to ni nnkan ṣe pẹlu oun, nitori iṣẹ to wa niwaju oun pọ ju lọ
Agba oṣelu ọhun sọrọ yii nigba to n bawọn kopa nibi ipade apero kan ti ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba ta a mọ si League of Yoruba Media Practitioners, LYMP, ṣe pẹlu wọn laipẹ yii lori ẹrọ ayelujara.
O sọ pe wahala naa ko ṣẹṣẹ bẹrẹ,latigba ti ipolongo ibo ti wọn di kọja ti bẹrẹ, lo ni awọn kan ti n halẹ, ti wọn si n dunkoko mọ oun ninu ẹgbẹ naa paapaa ni Ogun West, toun ti jade, ko si si nnkan to faa ju pe Tinubu toun ṣatilẹyin fun un lati di aarẹ ilẹ wa.
Pẹlu ariwo ti Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun pa sita yii lo mu ki igbakeji alukoro ẹgbẹ naa, Oluṣọla Ogunsanya, sọ fun ninu atẹjade toun naa fi sita pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni Daniel ṣiṣẹ fun ati Gomina Dapọ Abiọdun lo gba Daniel lọwọ iṣubu, wọn ko ba ma ti ranti ẹ mọ ninu oṣelu.
Amọ, Sẹnetọ Gbenga Daniel, lakooko to n ba awọn oniroyin lede Yoruba ‘League of Yoruba Media Practitioners’, sọrọ, o ni gbogbo ọrọ ti wọn n sọ si oun ko tun iru kankan, bẹẹ loun si ti gba gbogbo rẹ mọra patapata.
O sọ pe "Agba maa n gba naa ni, eyi ti wọn ba sọ pe mo ṣe, bẹẹ naa lori, eyi to ṣe patako ni bi a ṣe maa ran awọn araalu lọwọ, ebi n pa awọn eeyan, ara n ni wọn, mo si n gba a ladura pe eyi ti wọn ni ki n lọọ ṣe, Ọlọrun a fun mi lokun ati agbara lati ṣe e, bẹẹ lo si maa ri i.
Daniel wa pari ọrọ ẹ pe "Mo fẹẹ fi ye awọn eeyan pe ko si nnkan ti mo n le, ko si nnkan to n le mi, Ọlọrun ṣe daadaa fun mi lati kekere, ko si nnkan to wa ti mo n le ju pe ka fi ilu wa silẹ ju bi a ṣe ba a. Nigba ti mo jẹ gomina, a ṣe iwọn ti a le ṣe, awọn to n ṣe e lọwọ naa, nigba ti wọn ba ṣetan, awọn mi in naa a tun gbe e lati ibẹ lọ siwaju, bo ṣe ri niyẹn."
No comments:
Post a Comment