Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ rere nibẹrẹ lakooko yii- Ajadi Oguntoyinbo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 16 July 2023

Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ rere nibẹrẹ lakooko yii- Ajadi Oguntoyinbo


 

Ambasadọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, to jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP,nipinlẹ Ogun, ninu ibo to kọja yii ti sọ pe bi nnkan ṣe n lọ yii,  Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, n gbe awọn igbesẹ to daa, to si lo agbara wọn daadaa, ati pe o wu oun naa lati darapọ mọ ọn lati ba a ṣiṣẹ pọ.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii, lakooko to n gba ẹgbẹ akọroyin Yoruba, iyẹn League of Yoruba Media Practitioner, lalejo ni ọfiiṣi ẹ, lọsẹ to kọja, o sọ pe oun jẹ ẹnikan to fẹran lati maa wa nibi ti wọn ba ti n ṣe ohun to le mu aye araalu dara. Afojusun oun si ni lati darapọ, ki oun jiṣẹ t’Oluwa ran oun fun Naijiria ninu iṣakoso yii bo ṣe n lọ.

 

Oguntoyinbo to tun jẹ akọroyin, to jẹ alakooso ileeṣẹ ‘’Bullion Go-Neat Global Ltd’’ ti wọn ti n ṣe ohun mimu amarale fawọn ọkunrin, iyẹn Coco-Samba, tun sọ pe,o ṣe pataki kijọba Tinubu fi kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ.

 

O ni ‘’Ẹgbẹrun lọna igba (200,000) ko pọju gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju, nitori nigba ti wọn ti fowo kun owo epo, ni gbogbo nnkan ti gbowo lori, ti inira si ti pọju fawọn araalu’’

 

O  tun mẹnuba a pe o yẹ ki wọn mojuto ipese ina mọnamọna,ki ileeṣẹ apinnaka pọ bii ti ẹlẹrọ ibara ẹni sọrọ, ki wọn jẹ ki ifiga-gbaga wa laarin wọn, o ni nipa bayii,awọn araalu yoo le fi wọn ṣakọ lati ra a nibi to wu wọn.

 

Lori bi oludije gomina ọhun ṣe fidirẹmi ninu ibo to kọja naa, o sọ pe ko si nnkan to fa a bi ki ṣe ẹni toun fi ọkan tan, toun gbẹkẹle laimọ pe oun ni yoo tun lọ ta oun fawọn ọjẹlu, iyẹn alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Sunday Ọlapọsi Ọginni.

 

 O ni, ‘’ Ko sohun to jẹ ki n ri ijakulẹ ninu idibo to kọja yẹn ju pe mo fi ọkan tan eeyan lọ, awọn eeyan dẹ n pe mi si akiyesi pe ki n ṣọra fun alaga ẹgbẹ wa nigba naa, ti mo ti jade fun ipoo gomina nipinlẹ Ogun nigba yẹn, iyẹn Sunday Ọlapọsi Ọginni, emi ni mi o gbọ, ti mo ti gba pe ko sẹni to le ta mi bi mo ṣe jẹ ọdọ yii, to dẹ jẹ pe Oluwa lo ran mi niṣẹ naa lati sin ilu yii, lati mu awọn eeyan kuro ninu ìyà.

 

Oguntoyinbo ṣalaye pe  o ku ọsẹ kan ki ibo waye ni Ọlapọsi Ọginni lọọ darapọ mọ PDP, to ta mi to tun gbowo ori mi. O lọọ sọ fun wọn pe a o dije mọ, pe a ti darapọ mọ wọn.

 

O ni oun ti oun fẹẹ dije ko mọ nnkankan,awsn kan an ri fidio nibi to ti lọọ ba awọn Ladi Adebutu ṣepade, to n pariwo PDP lai ba oun sọ nnkankan.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ‘’Titi to fi ku ọtunla ta a maa dibo lo fi tan mi. Mo kabaamọ pe mo mọ ẹni to n jẹ Ọlapọsi Ọginni. Ẹyin ọdọ tẹ ẹ ba gbọ orukọ rẹ, ẹ ma duro o, ẹ sa lọ ni. Mo gbe igbesẹ lati fi to ẹgbẹ wa lapapọ leti, wọn si pe e lẹẹmẹta,ṣugbọn ko yọju si wọn, ohun ti wọn ṣe yọ ọ lẹgbẹ niyẹn’’

 

 O waa sọ pe pẹlu nnkan ti Ọginni foju oun ri yii ko ni ki oṣelu yọ lẹmi oun,ati pe ipo aarẹ lo ku toun yoo dije fun bayii, iyẹn lọdun 2027.

 

Ọkunrin yii tun sọ pe, ‘’Oluwa lo ba mi sọrọ pe ki n dije funpo naa, labẹ asia ẹgbẹ NNPP yii naa si ni ma a ti jade ni 2027. Ki i ṣe fun ifẹ ara mi, bi ko ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ti mo gbagbọ pe wọn gbọdọ kuro ninu iṣẹ ati oṣi.

 

O sọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ ti yoo yi nnkan pada fun NNPP,nitori nilẹ Hausa, ẹgbẹ wọn rọwọ mu, ṣugbọn nilẹ nilẹẹ Yoruba, owo lọwọ ẹyin nilẹ ni wọn n ṣe, o ni iṣẹ ti n lọ lati jẹ ki wọn mọ pe a ko le maa tọ oju ọna kan naa lọ lai dan ibo mi-in wo, bi asiko ba si to, o da oun loju pe didun lọsan yoo so.

Ni ti ohun mimu amara ọkunrin le, Coco Samba ti ọkunrin yii tun n gbe jade, o ni oun ki i lọ sọsibitu lọọ gbawosan, tewe-tegbo toun ti n lo lati kekere loun ṣi n lo titi diwoyi, nigba toun si ti ṣewadii ewe to le wulo fawọn ọkunrin bii toun loun ṣe gba ileeṣẹ NAFDAC lọ pe oun fẹẹ bẹrẹ ẹ, wọn si faṣẹ si i. Bẹẹ lo si ṣe ti kinni naa n ṣiṣẹ lọ bi arira fawọn ọkunrin ti wọn fẹẹ ṣe deede lọdọ aya wọn.

No comments:

Post a Comment

Pages