Jamiu Ademoye
Ẹsẹ o gbero ni ṣọọṣi Sinagọgu,to wa ni Ikọtun, niluu Eko, lọjọ kejila,oṣu yii, nigba tawọn ọmọ ijọ naa ṣayẹyẹ ọgọta ọdun, ọjọọbi oludasilẹ ijọ ọhun, iyẹn T. B Joshua, ẹni to jade laye ni nnkan bi ọdun meji sẹyin.
Bo tilẹ jẹ pe iranṣẹ Ọlọrun naa ti dagbere faye sibẹ, awọn ọmọ ijọ ẹ atawọn alejo pataki ti wọn fiwe pe peju pesẹ lati sajọjọ ọjọọbi ọhun lẹyin iku ẹ.Pẹlu orin ọpẹ, ariya ati ijo to fi mọ awọn ẹri iyanu ti ọkunrin naa ṣe nigba to wa laye, ni wọn fi sami ayẹyẹ ọjọọbi ọhun.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Wọn bi ojiṣẹ Ọlọrun, T.B . Joshua, lọjọ Kejila , oṣu kẹfa, ọdun 1963, ni Arigidi- Akoko, nipinlẹ Ondo.
Awokọṣe rere ni wọn sọ pe o jẹ, ẹni ti wọn lo koju iṣoro pupọ lati inu oyun, to lo oṣu mẹẹẹdogun ninu iya ẹ, idi niyi ti wọn fi n pe e ni Temitọpẹ. Ọpọ ipenija la gbọ pe o koju lati kekere, ko to di pe o gbọ ipe lọdun 1989, lẹyin awẹ ogoji ọsanati ogoji oru.
Lẹyin naa ni wọn da ijo " SCOAN" silẹ nii Agodo-Egbe, ki wọn to tẹdo si Ikọtun , to si jẹ Sinagọgu, ile ijọsin fun gbogbo agbaaye.
Ọpọ awọn to si wa nibẹ lọjọ naa ni wọn jẹri sii pe ojiṣẹ Ọlọrun gidi ni T.B. Joshua n ṣe, nigba to wa laye.
Yoruba sọ pe aṣeyọri ọkunrin, atilẹyin lyawo ko nii gbẹyin, awọn eniyan gbe oṣuba fun iyawo oloogbe T.B Joshua , Evelyn Joshua, fun akitiyan itẹsiwaju ibi ipagọ sinagọgu to n gbe ru sii lẹyin iku ọkọ rẹ.
No comments:
Post a Comment