Ṣẹgun Ṣowunmi ki Ribadu ku oriire fun ipo tuntun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 15 June 2023

Ṣẹgun Ṣowunmi ki Ribadu ku oriire fun ipo tuntun



Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ọkan lara agba ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti ranṣẹ ikinni ku oriire si Mallam Nuru Ribadu, fun ipo tuntun gẹgẹ bi oluranlọwọ pataki fun aarẹ lori eto aabo lorileede yii.

Ninu atẹjade ti ẹni to ti figba kan jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP,  ninu ibo abẹle fi sita, lo ti sọ pe ko digba ti wọn ba tun ṣe awitunwi asan ipo tuntun ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, yan ọkunrin naa si jẹ eyi toun nigbagbọ pe o le ṣe bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Bẹẹ lo tun lo akoko naa lati fi to ọkunrin naa leti  lori awọn iriri ipenija to ti ni nipa aabo lati nnkan bi ọgbọn ọdun ti ko tii sẹlẹ ri. O ni lara ni ti ijọba Dapọ Abiọdun to faye gba awọn janduku, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Ṣẹgun Ṣowunmi fi kun ọrọ ẹ pe bi Dapọ Abiọdun ṣe ko tọọgi ti wọn doju ija kọ oun niwaju kootu nigba toun fẹẹ lọ ṣe ojuṣe oun jẹ abuku nla foun, eyi to ni o ṣoju awọn ọlọpaa atawọn oniroyin.

O ni ibanujẹ ẹdun ọkan lo jẹ pe Dapọ Abiọdun, to jẹ olori alaabo nipinlẹ Ogun, dakẹ bi ẹni ti ko gbọ nnkaknkan tabi ti nnkankan ko ṣẹlẹ. O ni oun sọ eleyii ki Ribadu le mọ  pe bo ṣe n ṣẹlẹ niyii nilẹ Hausa, to fi mu kawọn kan maa ko ara wọn jọ.

O waa rọ Ribadu lati ṣewadii nipa iṣẹlẹ to waye ọhun, ko si ṣe ikilọ fawọn oloṣelu paapaa julọ Gomina Dapọ Abiọdun lati kọwọ ọmọ ẹ bọ aṣọ, lati ma ṣe gba igbakugba laaye.

Ṣẹgun Ṣowunmi tun ṣalaye pe pẹlu bo ṣe fẹẹ bẹrẹ iṣẹ lati maa sakoso aabo orileede yii bẹẹ ni iru awọn eeyan bi toun yii naa n ṣiṣẹ takuntakun lori bi orileede yoo ṣe ṣiṣẹ.O ni o le beere lọwọ Aarẹ Tinubu, nipa ijọba tiwa-n-tiwa, yoo si jẹ ko mọ pe wọn ja, wọn si bori pẹlu ifarasilẹ awọn eeyan pataki  lawujọ.

O waa rọ oludamọran pataki fun eto aabo tuntun naa lati ṣagbeyẹwo awọn nnkan toun sọ fun yii, ko si ṣiṣẹ le lori, lati ma ṣe jẹ ki laala awọn araalu ko ja si asan. O ṣeleri fun pe oun yoo ma ṣe atilẹyin fun nigbogbo igba, o ni oun mọ pe tiẹ yatọ sawọn kan, bẹẹ lawọn si fi adura ran-an lọwọ lati le ṣe aṣeyọri.


No comments:

Post a Comment

Pages