Ọkunrin naa sọrọ yii lakoko to n jabọ iṣẹ irinju wọn laarin oṣu kẹrin si ikarun tọdun yii, eyi to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni ọfiisi wọn to wa niluu Abẹokuta. O sọ pe awọn ri ọkọ nla bọọsi to jẹ tokunbọ meji , eyi tawọn fayawọ gbe gba ọna ẹnubode Ohumbe wọlé gbà, iyẹn lọjọ Kẹẹẹdogun, Oṣù Karùn-ún.
Bakan naa lo tun ni awọn ri mọto meji mii-in ti nọmba wọn jẹ JTHN9CPO6018610 àti JTGHN9CP7P6019835,gbà lọ́wọ́ lọna Sawonjo si Imasayi, lọjọ́ Aje, Mọnde, ọjọ́ kọkàndínlọgbọn oṣù karùn-ún, ọdún yìí.
Bamidele tun fi kun ọrọ ẹ pe lara nnkan ti wọn tun ri gba laarin oṣu kan ọhun ni baagi irẹsi t, ẹgbẹrun mẹfa ati ẹẹdẹgbẹrun lemẹrinlelogun, 6,924, epo bẹntiro, aloku taya ọkọ, egbògi oloro àti àwọn nǹkan mi-in tí kò bófin mu
O ṣalaye siwaju pe iye owo gbogbo nnkan táwon rí gbà lọ́wọ́ àwọn òní fayawo laarin oṣù kẹrin si oṣù kàrún-un, ọdún jẹ́ miliọnu lọna ọọdunrun le marundinlogoji,ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin le marun-undinlọgọta ati ẹẹdẹgbẹrun Naira. Gbogbo ẹrù tawọn si gba yii lo wà nibamu pẹ̀lú òfin Naijiria.
O tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe, ‘’A ti láǹfààní láti pa owó wọlé dáadáa sapo ìjọba. Ó ti tó nǹkan bí mílíọ̀nù mẹtalelọgbọn ni ifewera pẹ̀lú Mílíọ̀nù mẹ́wàá tá a pa wọlé lọdun to kọjá láàrin àkókò yìí. Bí a bá ní ká gbé èyí lórí ìdá, ó ti tó ìdá mọkandinlàádọ́rin ni ifewera sí tọdún to kọjá.
‘’ Laarin àkókò yìí a ti láǹfààní láti ṣe ètò pẹ̀lú àwọn olokoowo láti mọ bi ọ̀rọ̀ ajé wọn ṣe le túbọ̀ gbèrú sí i. A ti láǹfààní láti ṣètò igbani-nimoran, idalekọọ. A ti jẹ́ kí wọn mọ bí wọn ṣe lè máa tẹle òfin to de gbígbé ẹrú wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè lọ́nà ẹtọ ati àǹfààní tí yóò ṣe fún ìjọba’’
Ọga asọbode ọhun waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ gbogbo awọn àjọ ẹsọ alaabo mìí-in, lori bi wọn ṣe n fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati gbogun tawọn fayawọ yii, eyi to mu ki iṣẹ wọn rọrun daadaa, to si mu aṣeyọri jade.
No comments:
Post a Comment