Nnkan ko sẹnure lonii, niwaju kootu majisireeti to wa ni Iṣabọ, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, nigba tawọn tọọgi oloṣelu din dundun iya fun Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP atawọn ọmọ ẹgbẹ naa kan.
Nibi igbẹjọ ibo gomina ti Ladi Adebutu, to dije fun gomina nibi ibo ti wọn di kọja naa pe Gomina Dapọ Abiọdun, eyi ti wọn bẹrẹ lonii, la gbọ pe awọn tọọgi naa pẹlu ẹgba pankẹrẹ lọwọ yabo iwaju ile-ẹjọ ọhun, ti wọn ko si beṣu bẹgba, ti wọn ko bo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ti wọn wa nibẹ.
Pẹlu bawọn ọlọpaa atawọn agbofinro ṣe pọ to lẹnu iloro ile-ẹjọ naa, awọn tọọgi ọhun ko bikita bẹẹ lawọn alaabi ilu yii ko ri nnkan ṣe si, iran ni wọn n wo wọn.
Bi Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ṣe debẹ, to faraha ẹ han awọn agbofinro, ṣe lawọn tọọgi yii yabo, ti wọn si bẹrẹ si ni fi ẹgba to wa lọwọ wọn dabira sii lara, ori gan-an lo ko yọ, to fi raye sa lọ.
Gbogbo agbara tawọn agbofinro atawọn alaabo ilu ni ni wọn da lati le awọn tọọgi naa lọ ko to di pe alaafia bẹrẹ si nijọba nibẹ, amọ sibẹ naa ṣe ni wọn lawọn tọọgi yii foju wo awọn to wa nibẹ, ẹni ti wọn ba ti mọ pe PDP ni, alubomi ni wọn naa.
Ṣugbọn sa, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi ti sọ pe, awọn tọọgi ti Gomina Dapọ Abiọdun ran wa si kootu lo wa ṣiṣẹ naa. O sọ pe Gomina ti sọ ilu di tawọn janduku, digbolugi, ko tọọgi wa si kọọtu. O ni nnkan tawọn ba lọ sibẹ ni lati foju ri bo ṣe n lọ
No comments:
Post a Comment