Ganzallo fọkàn aráàlú balẹ̀ lórí ẹ̀mí àti dúkìá wọn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 4 June 2023

Ganzallo fọkàn aráàlú balẹ̀ lórí ẹ̀mí àti dúkìá wọn


  Ọga agba fun ikọ ẹṣọ alaabo So-Safe Corps,Dokita Sọji Ganzallo, tun ti muu da gbogbo awọn ara ipinlẹ Ogun loju pe wọn yoo tubọ maa tẹsiwaju lati rii  pe abo to peye wa fẹmi ati dukia wọn.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko ti wọn pari ayẹyẹ idanilẹkọọ ọlọsẹ mẹta, eyi ti wọn ṣe fawọn ọmọọṣẹ wọn ti wọn to ọgọrin, to waye ni ibudo ti wọn ti kọ wọn niṣẹ, Ilaro. O sọ pe fun ọpọ ọdun sẹyin, ti jẹ anfaani nla lori bi wọn ṣe le fopin si iwa ọdaran lawujọ.

 

Ọga agba naa tun sọ pe ibudo ti wọn ti maa n kọṣẹ ọhun ti mu igbooro bawọn ọmọọṣẹ wọn lori bi wọn yoo ṣe maa ṣiṣẹ wọn pẹlu igboya, gẹgẹ bi eyi ti wọn yan laayo lọkan ara wọn lati fi sin ilẹ baba wọn.

 

Bẹẹ lo sọ pe ọpọ iriri ati idanilẹkọọ ti wọn ti gba lati ọdọ awọn ọlọpaa ni Eleweran,ajọ to n gbogun ti ogun oloro, iyẹn NDLEA, awọn agbofinro lo ti mu aṣeyọri ba So-Safe Corps ni aimọye igba.

 

O waa dupẹ lọwọ Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gomina ipinlẹ Ogun, fun bo ṣe fi ikọ alaabo wọn si eto isuna fọdun 2023, eyi to lo fi ọkan awọn oṣiṣẹ wọn lọkanbalẹ lati fi le ṣe ju bi wọn ṣe n ṣe lọ nidii iṣẹ ọhun.

 

Ninu ọrọ akọwe agba nileeṣẹ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun,  Dokita Akinlesi Rotimiolu, to ṣoju fun alakoso wọn, Ọgbẹni Ṣẹgun Ibirinde, mu da awọn alaabo naa loju pe gbogbo ọna nijọba yoo fi maa ṣatilẹyin fun wọn lati le rii pe abo to peye wa fun ẹmi ati dukia araalu.

 

Bẹẹ lo tun rọ gbogbo awọn olukopa lati lo gbogbo ọgbọn ati imọ ti wọn ri lakooko idanilẹkọọ naa fawọn ti ikọ alaabo yooku, ki wọn si jẹ ki iṣẹ ti wọn n ṣe mu wọn lọkunkun dun.


No comments:

Post a Comment

Pages