Agba oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bọde George ti sọ pe oun ko ni ikunsinu kankan pẹlu Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, o kan jẹ pe ipinnu wa lo ṣe ọtọọtọ, ti onikaluku wa ni oore-ọfẹ si.
Ninu atẹjade ti ẹni to ti figba kan jẹ gomina laye awọn oloogun laarin ọdun 1987 si 1990, fi sita lo tun ti sọ pe gbogbo ahesọ tawọn kan sọ pe oun ti gba lati gba iṣẹ oṣelu lọwọ aarẹ ọhun ko ri bẹẹ rara.
O sọ pe pẹlu ipo toun wa, oun ti dagba lati gbaṣẹ oṣelu kankan, O ni gbogbo awọn to wa nidii ẹ jẹ ọlọgbọn dori ẹja mu, ti wọn gbe nnkan ti ko ṣẹlẹ jade.
Bọde George tun sọ pe,’’ Pẹlu bi mo ṣe fẹẹ pe ọgọrin ọdun lori eepẹ, ki wọn fun mi laaye lati ki n gbadun ipo mi gẹgẹ bi oludamọran ati ọmọ orileede rere ninu iṣejọba tuntun. Ki ẹnikẹni ma ṣe darukọ mi lati fi polowo iroyin’’
O ni adura oun ni pe ki awọn ọmọ orileede yii wa ni oke agba, nitori oun ko fẹran lati maa rii pe wọn wa ninu irira. O ni igbe aye irọrun ati aabo wọn gbọdọ jẹ ijọba logun.Lori bi wọn ṣe lawọn ẹgbẹ agba kan n wọna irẹpọ laarin agba oṣelu naa ati aarẹ Tinubu, o sọ pe oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n gbe igbesẹ naa.
Oloye Bọde George ni,’’ Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn to n gbe igbesẹ ki alaafia jọba laarin emi ati Tinubu, ṣugbọn mo fẹẹ ko wa ninu itan pe mi o ni ikusinu kankan pẹlu ẹ,iyatọ kan to wa nibẹ ni pe onikaluku wa lo ni ipinnu tiẹ,eyi ta a ni oore-ọfẹ si. Mo ki i ati gbogbo ọmọ Naijiria. Amọ, ko si akoko fun mi lati gba iṣẹ oṣelu, awọn to si n gbero ẹ fun mi, ki wọn yọ mi kuro ninu ẹ’’.
No comments:
Post a Comment