Ilu Ikorodu gbalejo lojo ti iyawo Oba Ara si ileewe tuntun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 28 May 2023

Ilu Ikorodu gbalejo lojo ti iyawo Oba Ara si ileewe tuntunGongo so lojo Abameta, Satide, ana, lagbegbe Oba Olaide,Ibeshe, niluu Ikorodu, nigba ti Olori Afolashade Aina Onimole, to je iyawo gbajumo olorin emi nni Rotimi Onimole, topo awon eeyan mo si Oba Ara, si ileewe tuntun.

Ileewe naa to n je Rebian Care Play School, ni Wolii Femi Jeremiah Okikiola ti ijo The Light and the Word Salvation Ministry, ba won si lojo naa, leyin ti won ya a si mimo

Nigba to n soro lojo naa, Olori Afolashade so pe oun dupe lowo Olorun fun pe o je ki erongba oun lati da ileewe sile di mimuse, nitori lati nnkan bi odun mesan-an seyin ni ipinnu yii ti wa lokan oun.


O salaye pe lati kekere loun ti feran awon omode, lati maa setoju won,toun si ni lokan pe oun yoo da ileewe tiru nnkan bee yoo ti maa waye sile.

Bee lo so pe gbogbo igba toun fi wa lorileede Amerika, awon eko to nii se pelu awon nnkan wonyii loun lo, toun si jade pelu iwe eri.


Iyawo Oba Ara tun fikun oro e pe lati bi odun mesan-an toun gbiyanju,oun waa dupe lowo Olorun pe o ni akoko ti to bayii.

O waa lo akoko naa lati fi dupe lowo oko e, iyen Olurotimi Onimole, Oba Ara fawon ipa to ti ko ninu igbe aye e ati pe gbogbo igba lo maa n duro ti oun lati le je ki ala oun se.O so pe lati ibere pepe ni oko oun yii fi okan kan ba oun dogba lori idasile ileewe yii, pelu owo, eyi to ya oun lenu ni tile ti o fi jo oun loju, ti won fi ko ileewe naa, o ade ori ti ko se lafiwe ni.

Bee ni Olori Onimole yii tun lo ayeye ojo naa lati fi ileewe naa sori mama e, o ni bi 
abiyamo rere to duro ti omo, nitori ipa to ko ninu aye oun ko se e gbagbe lailai.

Lara awon to fere da won lara ya lojo naa ni Hajiya Hawawu Oriyomi omo Ariyo atawon olorin emi mii-in.

No comments:

Post a Comment

Pages