Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, to ti figba kan dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ninu awọn ipinlẹ mẹfa to wa nilẹ Yoruba, iyẹn Ogun, Eko, Ọṣun, Ekiti, Ondo ati Ọyọ, mẹta ninu wọn ni yoo pari saa akọkọ wọn laipẹ yii.
Awọn naa ni Ogun, Eko ati Ọyọ.Ninu ipinlẹ mẹta ọhun, o sọ pe Eko pari ti wọn pẹlu ṣiṣi awọn iṣẹ akanṣe ti ko lonka atawọn ileeṣẹ olokoowo aladaani ati tijọba. Bẹẹ lo ni Ọyọ pari ti wọn pẹlu apero okoowo niluu London ati ṣiṣi ile igbalode tipinlẹ naa to wa ni Abuja.
O ni oun waa gbadura pe kin wa ni Ogun ṣe lati fi pari saa akọkọ wọn, ofo lo pe, o ni wọn ko ṣe nnkankan, amọ asiko ti itan yoo yatọ, loun ko le sọ, nitori oun ko le sọ igba ninu ijọba dẹmokireesi tipinlẹ Ogun yoo fi jẹ awokọṣe.
Ṣẹgun Ṣowunmi tun sọ pe, ‘’ O jẹ ẹdun ọkan pe gbogbo awọn olugbe,atọmọ ipinlẹ Ogun, ti wọn tun jẹ ololufẹ ki wọn ma ṣe sun orun asunpiye, lati ṣe atilẹyin fun ijọba to wa lode ki wọn ma ṣe sun lẹnu iṣẹ, ki wọn le ṣe aṣeyọri’’.
O fikun ọrọ ẹ pe oun korira kawọn aṣaaju maa fọrọ araalu ṣere, ki wọn ma le ṣe awọn nnkan ti yoo mu ipinlẹ naa goke agba. O ni awọn olubaniṣiṣẹ pọ ti wọn yoo ba ijọba ṣiṣẹ pọ gbọdọ gbaradi, ki wọn si ni okun ati agbara lati gbaṣẹ naa.
O ni eyi to yẹ ko jẹ erongba ọkan wọn ni lati okoowo ko gboro si ninu iṣejọba tuntun, o ni ki wọn mọ daju pe akoko ti wọn wa yii wọn wa ṣiṣẹ lati gbe Ogun soke ga ju bo ṣe wa lọ.
No comments:
Post a Comment