A fi Aje ọdun yii sọri Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi aarẹ tuntun- Aarẹ OPC New Era - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 23 May 2023

A fi Aje ọdun yii sọri Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi aarẹ tuntun- Aarẹ OPC New Era



Aarẹ fẹgbẹ Oodua People Congress, New Era, Oloye Rasaq Arogundade, ti sọ pe awọn ayajọ ọdun aje tawọn ṣe lati fi sọri Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati fi ko aje wọ orileede, tawọn si gbagbọ pe niwoyi ọdun to n bọ, nnkan yoo ti maa tuba tusẹ.

Saddam sọrọ ọhun lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ, nibi ayajọ ọdun aje tọdun yii, to waye lọjọ Aje, Monde, ọsẹ yii, ni Owode-Onirin, Agboyi-Ketu, niluu Eko, lo gbalejo ẹ.

O sọ pe gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ pe ati n gbaradi lati bura fun aarẹ tuntun lorileede yii, eyi to si jẹ ojulowo ọmọ Yoruba atata, idi niyii tawọn fi ṣe ọdun naa lati fi bẹ aje, ko le ba aarẹ tuntun naa ṣejọba ẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ko sẹni ti ko mọ pataki ti aje n ko lawujọ, gbogbo eeyan lo si maa n gbadura pe ko fi ile oun ṣebujokoo, nitori ẹ ni ẹgbẹ OPC New Era, ko ṣe fi ọdun aje ṣere rara, to si jẹ pe ọdọọdun lawọn maa n ṣe lati fi bẹ Olodumare, ko ma ṣe fi wọ́n wọn.

Amọ ti tọdun yii yatọ, nitori bi ipalẹmọ ibura Tinubu ṣe n lọ lọwọ bẹẹ naa ni agbarijọpọ OPC New Era, ko ara wọn jọ lati sọdun naa. O wa lo akoko ọhun lati fi rọ gbogbo ọmọ Naijira lati gbarukutu ti aarẹ tuntun naa, ki awọn ileri to ṣe lakooko ipolongo le di mimuṣẹ.

Bẹẹ lo tun rọ gbogbo awọn ti wọn sọ pe awọn lẹjọ ni kootu, ki wọn tete jawọ, nitori oun nigbagbọ pe wọn ko nii mu nnkan gidi bọ nibẹ, nitori o ohun to da gbogbo ọmọ orileede yii loju ni pe Tinubu ni Ọlọrun yan lati jẹ adari tuntun.

Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ OPC New Era, tun  sọrọ lori ọrọ ti ẹnikan sọ pe ilana ti Aarẹ Buhari fi silẹ, ni Tinubu yoo tẹle ninu ijọba ẹ, Saddam, sọ pe ko si nnkan to jọ, nitori aarẹ to fẹẹ ko gba sile naa mọ oun ko ṣe.

O tun sọ pe, Ipa pataki  ni aje maa ko lakooko yii  ti yoo yatọ gedegbe gan-an ni, bi ẹ ba wo ọrọ aje orileede yii nibi to de bayii, ko Aarẹ wa mọ,, ọsẹ meji to fẹẹ lọ, ṣe lo tun fẹẹ lọ yawo, kin ni nnkan to fẹẹ fowo naa ṣe, ṣe bo ni a n ta epo, nibo ni wọn ko owo ẹ si, aje n binu si wọn ni.’’

‘’Amọ aje taa n ṣe lonii yii, a fi n ṣe ipalẹmọ ibura Asiwaju Tinubu ni, o da mi loju pe nigba ti yoo ba fi di ọdun kan ti wọn yoo pe ọdun lori aleefa, bi wọn yoo ba wo aṣeyọri ẹ, ẹ o rii pe eto ọrọ je orileede yii yoo ti gun rege.

Ọkunrin naa tun wa sọ pe, ‘’ Mo fi akoko yii rọ awọn aṣaaju wa lati maa farabalẹ gbọ ikilọ ti OPC New Era, ba n ṣe fun wọn ni iru akoko bayii, Yoruba tọkantọkan to ni ifarajin ni wa, a si maa n lo iru anfaani bayi lati maa kilọ fun ijọba loorekoore’’

 O ni iru ẹ lo fẹẹ waye nibi ibo to waye kọja yii nipinlẹ Eko, nibi tawọn ajoji ọmọ ibo fẹẹ maa lalẹ hu lori ilẹ onilẹ, ti wọn  fẹẹ fi ge ika ti wọn fi jẹun, nipaṣẹ awọn iwakiwa ti wọn hu lakooko ENDSARS, pẹlu atilẹyin alakoso wọn, Nnamdi Kanu ti IPOB.

O sọ pe eyi to jẹ iyalẹnu lori ọrọ naa ni bawọn to jẹ ọmọ ti wa ṣe satilẹyin awọn ajoji ọmọ Ibo yii, ẹdun ọkan lo ni o si jẹ pe awọn ọmọ wa le maa woju awọn agbalagba atawọn ọba alaye. Wọn ti gbagbe pe odo to ba gbagbe orisun dandan ni ko gbẹ.

Bẹẹ lo tun sọ pe gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ipinlẹ Eko mule ti awọn odo, paapaa eyi to lagbara ju ti wọn pe ni  Olokun Iṣẹrin-ade. Eyi to ni ipo ẹ ko ṣe fi sẹyin, koda o ni titi di akoko yii ọpọ awọn ẹru ni wọn maa n gba aarin odo yii kọja.

 Ninu ọrọ Ọba Isiaka Adio Balogun Oyero,Ilufẹmiloye Kin-in ni,Alaketu tilu Ketu, ni Kosọfẹ, niluu Eko, olo ti sọ pe gbogbo eeyan lo n gbadura pe ki aje ko ba oun sun, ko ba oun ji, ki  o wa pẹlu oun titi lae.

O tun sọ pe ko si ọba, to maa fọwọ pa iṣeṣe loju, o ni kawọn eeyan to wa ni Iṣẹṣe ti wa,  O ni ko sibi ti wọn ki tii ṣe, koda ninu ẹsin igbagbọ ati musulumi, o sọ pe o wa, bẹẹ lo tun sọ pe isẹṣe yii naa lo bi ọba.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages