Ọgbẹni Akinọla Oruṣagbemi, to jẹ ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Labour, ni Agege, ipinlẹ Eko, ti ke gbajare sita pe ki awọn ọlọpaa lọ mu awọn kan ti wọn ti le danu ninu ẹgbẹ naa amọ ti wọn n gbero lati pa alaga awọn iyẹn Pasitọ (Arabinrin) Dayọ Ekong, nitori ipo alaga.
Ọkunrin naa sọrọ lonii lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ, o sọ pe ṣe lawọn eeyan ọhun ati alaga ti wọn yan laarin ara wọn yii n lepa ẹmi obinrin naa. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii ni wọn ta awọn lolobo pe awọn eeyan ọhun gbero lati wa da ọfiisi wọn ru, lati ṣe awọn nijanba, amọ ti wọn ko le wa lọjọ naa.
O sọ pe ki wọn ma ba a tun pada wa lawọn ṣe tete pariwo sita pe kawọn ọlọpaa atawọn agbofinro ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ lati wa mu awọn eeyan ọhun, ki wọn si beere ọrọ lọwọ wọn idi ti wọn fi n le ẹmi alaga wọn naa.
O sọ pe, ‘’Lori ọrọ alaga ẹgbẹ wa, Dayọ Ekong, mo fi akoko yii pe awọn ọlọpaa lati mu awọn kan ti wọn n lepa ẹmi alaga wa yii, a ti le awọn eeyan naa danu ninu ẹgbẹ nitori awọn aṣemaṣe kan, amọ ti wọn ko fẹẹ jawọ, ṣe ni wọn n lepa ẹmi alaga ẹgbẹ wa. Lọjọ Furaide to kọja yii, wọn ta wa lolobo pe wọn n bọ ni ọfiisi ẹgbẹ wa, ni Eko, nibi yii pẹlu awọn tọọgi lati waa da wahala silẹ, lati ṣe wa nijanba.
Oriṣagbemi tun ṣalaye siwaju pe titi di akoko yii lawọn si n sọ pe Dayọ Ekong, lawọn n fẹ, Ọlorun si ri awọn eeyan ọhun nilẹ ko to fi obinrin yii ṣe olori awọn, nitori o ti mọ pe oun lo le ṣe e, o si n ṣe irinajo ọhun, o tẹ awọn lọrun, bo ṣe yẹ ko lọ, lo n lọ, pẹlu awọn oloye atawọn ọmọ ẹgbẹ to n ba ṣiṣẹ.
O tun sọ pe,’’ A fẹẹ ki awọn ọlọpaa ba wa so fun awọn eeyan naa pe nnkan ko gbodọ ṣe alaga wa,Ọlọrun ọba lo fi sibẹ, ki i ṣe ẹda,o si mọ pe oun lo le ṣe. Mo fi akoko yii rọ awọn ọmọ orileede yii ki wọn ba wa beere lọwọ wọn nnkan pato ti obinrin naa ṣe fun wọn.
Bakan naa lori igbẹjọ aarẹ to n lọ lọwọ, ọkunrin naa sọ pe awọn dupẹ pe ile ẹjọ ti dawọn lare, nipa Julius Abure, nnkan kan to ni o ku fun-un ni pe ko tẹsiwaju gẹgẹ bi alaga lapapọ, ko si wa ṣiṣẹ lori Eko, ki wọn le jẹ ki alaga wọn yii ko ṣiṣẹ ẹ, ki wọn ma ṣe yọ lẹnu. O ni bi wọn ba fi le yọ obinrin yii nipo naa patapata oun atawọn ọmọ ẹyin oun ti ṣetan lati fi ẹgbẹ naa silẹ.
O tun sọ pe, ‘’Lori ọrọ ẹjọ to n lọ lọwọ, gbogbo eeyan lo n wo awọn adajọ, ki wọn ranti ọjọ ti wọn yoo sun ti wọn ko ni ji mọ, ki wọn fi wo ẹjọ ti wọn fẹẹ da, ki wọn fi gbogbo omi ati ẹjẹ ara wọn da ẹjọ naa, pẹlu ibẹru Ọlọrun, ki wọn wo ẹni to wọle. Nitori gbogbo wa la mọ pe Peter Obi lo wọle, ẹni to ba maa di aarẹ orileede yii, ti ko ba ti bori ibo ni Abuja, pẹlu ida mẹẹdọgbọn, emi o ro pe o yẹ ki wọn sọ pe oun lo wọle’’
‘’Gbogbo eeyan lo si mọ pe Peter Obi, lo bori ni Eko, Rivers, ki wọn ba wa da ẹjọ naa bo ṣe yẹ ki wọn da a, ki atubọtan wọn le dara, ki wọn mọ pe awọn naa bi ọmọ, wọn ko si mọ ibi ti ọmọ wọn naa ma de,ajọ eleto idibo iyẹn INEC n sare kaakiri, awọn nnkan tawọn lọya Obi beere lọwọ wọn, wọn ko mu jade, ki wọn maa ṣe gba abẹtẹlẹ lati ta ẹri ọkan wọn, ki wọn ṣe bo ṣe yẹ’’
Bẹẹ lo sọ pe ko yẹ ki ibura waye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii gẹgẹ bi awọn kan n ṣe gbero ẹ, nitori gbogbo wọn ni mọ pe igbẹjọ si n lọ lọwọ, o ni ki wọn jẹ jawọn adajọ gbe idajọ wọn dide, ki wọn si jẹ ki gbogbo aye mọ ẹni to wọle gan-an.
O beere pe kin ni nnkan to n kan wọn loju ti wọn ko fẹẹ ki idajọ waye ki ibura to waye, o waa rọ Aarẹ orileeede yii, Mohammadu Buhari, lati ṣagbeyẹwo ẹ, ko ma ṣe gba fun wọn ki ibura waye.
No comments:
Post a Comment