Adajọ ni ki Ejigbadẹrọ, ajagungbalẹ ti wọn fẹsun kan pada satimọle l’Ekoo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 19 May 2023

Adajọ ni ki Ejigbadẹrọ, ajagungbalẹ ti wọn fẹsun kan pada satimọle l’Ekoo



 

Ọkunrin kan, ajagungbalẹ niluu Eko, Abiọdun Ishọla Ejigbadẹrọ, ni Adajọ majisireeti Yaba, Eko, A.O Olatunbosun, ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi pamọ satimọle titi di ọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun yii.

 

 Ẹsun pe oun atawọn eeyan ẹ kan ti wọn wa bayii, Ibraheem Fasasi Bello, Rasaki Ọdunoye, Taofik Ajọsẹ, Azeez Amọdu, Sunday Dada, Sọliu Ọdunoye,  Mukaila Aliu, Abdulganiyu Adeleke, Amidu Ṣeidu, Mutiu Bello, Solomon Aliya, Sọdiq Anishẹrẹ ati Ṣakiru Sunday, gba ilẹ onilẹ lagbegbe Alimọshọ ni Eko.

 

Ninu iwe ipẹjọ ti nọmba ẹ jẹ A/52/2023, ni wọn ti fẹsun marun-un ọtọọtọ kan Ejigbadẹrọ, lara ẹ ni ipaniyan, titọju awọn nnka ija oloro lọna aitọ. Ṣugbọn Adajọ to n gbẹjọ naa sọ ki ọkunrin yii si lọ maa sinmi latimọle titi digba ti yoo fi gbaṣẹ nileeṣẹ eto idajọ lori igbẹjọ ọhun.

 

Iwe ipẹjọ ọhun lo ka bayii, Abiọdun Ishọla Ejigbadẹrọ atawọn kan ti ṣi n wa titi di akoko yii lọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, lagbegbe Akowọnjọ, Alimọshọ, Eko, yawọ ori ilẹ awọn eeyan to n gbe nibẹ, lati ṣe wọn nijanba, eyi to lodi si ofin ipinlẹ Eko, tọdun 2015.

 

Awọn ẹsun mii-in ti wọn tun ka si lẹsẹ ni bo ṣe gba ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Olugbenga Bakare lẹsẹ, ti onitọhun ko si gbadun. Bẹẹ ni wọn tun sọ pe ṣe o lo orukọ olorukọ iyẹn Ọmọọba Iṣọla Akapo lati fi ṣe akọsilẹ ẹjọ ti nọmba ẹ jẹ No ID/9661LMW/202.

 

 Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan Ejigbadẹrọ atawọn eeyan pe wọn lọ ṣe ayederu iwe ilẹ, ti wọn fi ọjọ kejidinlogun, oṣu kejila, ọdun 1974, si i, eyi ti wọn sọ pe ko si ni orieede yii ati ni oke-okun, ati pe ṣe lo tun pe ara ẹ ni mọlẹbi Olubunmi fun ileeṣẹ ijọba ibilẹ ati ọrọ oye, nijọba ibilẹ Alimọṣọ, ni ero lati jẹ baalẹ ilu naa.

 

Gbogbo awijare Samson Ajala, to jẹ agbẹjọro ọkunrin naa lati rii pe wọn gba beeli onibaara ẹ lo ja si pabo, nitori ṣe ni Adajọ Olatunbosun ESQ, sọ pe ko si nnkan to jọ ọ lakooko yii titi digba ti amọran yoo fi waye lati ileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Eko.

 


No comments:

Post a Comment

Pages