Ọmọọba Adesọyin, alaga tuntun fẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko, ti sọ pẹlu idaniloju pe oludije wọn fun ipo aarẹ ninu ibo to kọja iyẹn Peter Obi, ni yoo jawe olubori nibi igbẹjọ to n lọ lọwọ, ti yoo si di aarẹ laipẹ.
Ninu atẹjade ti alukoro ẹgbẹ ọhun, Ọnarebu Okufuwa Samad Oluwatoyin, gbe jade lorukọ alaga wọn, lo ti sọ pe gẹgẹ bi ọrọ Yoruba to sọ pe igbe aye wa ko da lori boya wahala wa bi ko ṣe bi a ba ṣe da wọn lohun si.
O tun mu da awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Eko loju pe gbogbo awọn aawọ to n waye ko le ṣe ko maa ribẹ ninu oṣelu, amọ yoo niyanju laipẹ, ti nnkan yoo si maa lọ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Bẹẹ lo tun tan imọlẹ sii pe akoko alaga fidhẹ ẹgbẹ naa tẹlẹ, iyẹn Arabinrin Pasitọ Dayọ Ekong ti pari lati oṣu kẹrin ọdun yii
Ọmọọba Adesoyin Olumide, alaga tuntun ọhun, to ni akọsilẹ nipa bi wọn ṣe yanju wahala ninu oṣelu tun fikun ọrọ ẹ pe wọn ko le fi tipa mu alaafia jọba, bi ko ṣe nipa igbọra-ẹni-ye ati ọpọlọ ni wọn le fi yanju ẹ.
O waa pari ọrọ ẹ nipa gbigbe oriyin fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour, lori bi wọn ṣe n fi tọkantara ṣiṣẹ lati le jẹ ki igbe aye irọrun wa lorileede yii. Pẹlu idaniloju pe ibo aarẹ tawọn kan ji gbe, Peter Obi yoo gba a pada nile-ẹjọ ti wọn lọ.
No comments:
Post a Comment