Wahala yoo bẹ bi ẹ ba yọ Dayọ Ekong, alaga ẹgbẹ oṣelu Labour l’Ekoo-Oriṣagbemi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 12 May 2023

Wahala yoo bẹ bi ẹ ba yọ Dayọ Ekong, alaga ẹgbẹ oṣelu Labour l’Ekoo-Oriṣagbemi



Ọkan lara aṣaaju ẹgbẹ oṣelu Labou nipinlẹ Eko, Akinọla Oriṣagbemi, ti ke si awọn oloye ẹgbẹ naa lapapọ lati tun ero wọn pa lori bi wọn ṣe fẹẹ yọ Pasitọ Arabinrin Dayọ Ekong, to jẹ alaga ẹgbẹ naa lati tete tun ero wọn pa, bi bẹẹ kọ, wọn fẹẹ da wahala ti apa wọn ko nii ka silẹ.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko toun atawọn eeyan ẹ n ba awọn oniroyin sọrọ, nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu wọn. O sọ pe awọn fun Lamidi Apampa, to sọ ara ẹ di alaga ẹgbẹ apapandodo ni wakati mejidinlaadọta lati tun ero ẹ pa lori bo ṣe fẹẹ sọ ẹnikan ti wọn n pe ni Olumide di alaga wọn.

O ni gbogbo atilẹyin lawọn ọmọ ẹgbẹ Labour ipinlẹ Eko ṣe fun Dayọ Ekong, lati maa ṣe ijọba ẹ lọ, nitori o tẹ awọn lọrun, yoo si ko awọn jẹpẹ, nitori aṣaaju to ṣee muyangan, nitori ko sẹni to ba iranlọwọ de ọdọ ẹ, ti ki i dide si.

O ni, ‘’Emi Akinọla Oriṣagbemi, mo  fun alaga ẹgbẹ lapapọ ni wakati mejidinlaadọta, lati fi yanju ọrọ Olumide atawọn yooku ẹ Ko tu gbogbo awọn igbimọ to yan ka, nitori ko sẹni to mọ wọn.Ki Apampa ko kuro lori ipo to wa, nitori Agbẹjọro Abure lawa si mọ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ wa titi di akoko yii’’.

‘’Ki wọn ba wa da Dayọ Ekong pada gẹgẹ bi alaga wa, ti yoo lo ọdun mẹrin saa ẹ, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ wa lẹyin ẹ, ẹyin naa , ẹ woo, awọn aṣeyọri to ṣe ninu ibo to kọja yii, ninu aṣoju-ṣofin, a mu marun-un, ninu ibo ọmọ ile igbimọ aṣofin, a mu meji, ta a si tun ni awọn ẹjọ kan lati fi gba ẹtọ wa pada’’

O tun sọ pe bi wọn ko ba fẹ ko ogun ja, ki wọn tete gbe igbesẹ,ki wọn yọ Olumide, nitori oun mọ pe bi wọn ko ba ṣe bẹẹ ogun yoo ja.

No comments:

Post a Comment

Pages