Lati le fopin si awọn iwa aibikita tawọn ọmọleewe maa n hu lawọn ileewe girama, ijọba ipinlẹ Ogun pẹlu ajọṣepọ Banki Agbaaye, ti ṣe idanilẹkọọ fawọn ọmọleewe aladaani ati tijọba, ti wọn le ni ọgọfa lori ọna ti wọn fi le gba dẹkun awọn iru nnkan bẹẹ.
Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ nibi eto ọhun, Ọgbẹni Fatai Ọṣunsanya, to ṣoju Arabinrin Mosunmọla Owo-Odusi, alakoso fun akanṣe ayipada ọrọ aje nipinlẹ Ogun,sọ pe eto ọhun lawọn ṣe pẹle ajọṣepọ banki agbaaye lati fopin sawọn wahala to maa n waye laarin awọn ọmọleewe paapaa julọ nileewe ijọba ati lati ṣafihan ibudo kan ti yoo maa kọ wọn,tabi lo lakooko ti wahala ba waye.
O fikun ọrọ ẹ pe ọpọ awọn akẹkọọ nu wọn ku iku akusinu nitori wọn ni ọna lati fi sọ ero wọn sita nigba ti wọn ba lawọn idojukọ iru nnkan bayii. O waa ṣeleri pe pẹlu idanilẹkọọ tawọn n ṣe yii, o daju pe opin yoo de ba a, ko ni si ihalẹ, eebu, ija ati idojuti mọ laarin awọn ọmọleewe.
Ninu ọrọ Arabinrin Bamidele Makinde, to jẹ alakoso kn nileeṣẹ eto ẹkọ, to ṣoju kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, o sọ pe awọn ti gbe iru awọn eto ti wọn ṣe yii kaakiri bi ẹkun Ẹgba, Rẹmọ ati Yewa, ko to wa di pe awọn ṣe ni Ijẹbu, ni ipele si ipele.
Ọjọgbọn Arigbabu sọ pe asiko ti to lati fopin si wahala to n waye lawọn ileewe, eyi tawọn ọmọleewe kan maa n da silẹ. O sọ pe awọn ọmọleewe gan-an ni ipa Pataki lati ko, o wa gba wọn nimọran lati lo awọn ibudo ti wọn kọ naa lati maa fi ero ọkan wọn han sita nigbakigba ti wọn ba ba ipenija iru nnkan bẹẹ pade pẹlu ileri pe aabo to peye yoo wa fun wọn laarin wakati mẹrinlelogun, laini na wọn ni owo.
Arabinrin ẸwaJesu Faṣina toun naa wa nibi eto ọhun rọ awọn ọmọleewe lati maa sọrọ sita lakooko ti wọn ba a ba awọn nnkan bi ifipabanilopọ, eebu, ihalẹ pade, ki wọn ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni maa ko wọn laya jẹ
Pẹlu afikun pe Gomina Dapọ Abiọdun, tipinlẹ Ogun ko fi ẹtọ awọn ọmọde ṣere rara, nitori ẹ lo ṣe ni isakoso ẹ pese awọn bii agbẹjọro, dokita, siifu difẹnsi, sibi ibudo naa.
Bẹẹ lo sọ pe ofin kan wa nipinlẹ Ogun lati foju ẹnikẹni to ba a ba ọmọ ti ko ba tii to ọdun mejidinlogun sun, o waa lo akoko naa lati gba awọn ọmọleewe obinrin nimọran lati ma ṣe maa darin lọsan ati loru bẹẹ ni ki wọn sọra fun aṣọ iwọkuwọ. Ati pe ẹnikẹni ninu wọn ti wọn ba gba mu fawọn iru ẹsun bẹẹ ibi ti wọn ti maa kọ awọn ọmọ ti gbọn lọgbọn ni yoo ti bara ẹ
Bakan naa lawọn olori awọn akẹkọọ ti wọn wa nibẹ dupẹ lọwọ ijọba fun akanṣe eto nla ti wọn gbe kalẹ fun wọn pẹlu ileri pe awọn yoo jẹ ọmọ rere, bẹẹ lawọn yoo maa sa fawọn nnkan to le da wahala silẹ.
No comments:
Post a Comment