Inu ahaamọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ni meji ninu awọn ọmọọta ti wọn kọlu gbajumọ olorin ẹmi nni Dokita Oluwarotimi Ayinde Onimọle tawọn eeyan tun mọ si Ọba Ara wa bayii, lati ahaamọ la gbọ pe wọn yoo gba lọ sile-ẹjọ lọjọ kẹrindinlogun osu to n bọ lati lọọ ṣalaye ohun ti wọn ri ti wọn fi kọlu ilu mọ ọn ka olorin naa lasiko to lọọ kọrin niluu Ifẹtẹdo, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja lọhun-un.
Bakan naa la gbọ pe adajọ ile-ẹjọ ti wọn ko awọn meji tọwọ awọn ọlọpaa tẹ ọhun ti sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu Ọba Ara yii ni wọn gbọdọ ko wa siwaju oun lọjọ ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ, bẹẹ lo paṣẹ pe kawọn meji tọwọ tẹ ọhun si wa lahaamọ awọn ọlọpaa titi dọjọ ti igbẹjọ yoo waye.
Tẹ o ba gbagbe, nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe ni ọgba ileewe ‘High School Campus’, to wa ni Ifẹtẹdo, nipinlẹ Ọṣun, ni gbajumọ olorin ẹmi naa ti lọọ ṣere fun wọn,
Ohun ti a gbọ ni pe bi ọba ilu naa, to tun jẹ agbẹjọro, Ọba Akinọla Akinrere Latiri Olubọsin ilẹ Ifẹtẹdo, kuro loju agbo naa ni wọn sọ pe awọn janduku yii debẹ ti wọn si ko wahala ati iforo ẹmi ba gbogbo awọn to wa nibi ariya yii.
Ninu ọrọ Ọba Ara, lo ti sọ pe ’’ Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko si ẹni to farapa ninu awọn ọmọọṣẹ mi ta a jọ lọ,ṣe ni wọn kọlu wa gidi gn-an ni. Bi mo ṣe ri i pe wọn n bọ ni mo ti sare fun wọn lowo nla, sibẹ, wọn tun kọlu wa, ti wọn si ba mọto wa jẹ’’
O tun sọ pẹlu iyalẹnu pe awọn eeyan naa ko ni ibẹru Ọlọrun o, eeyan buruku ni wọn, ti wọn si buru gan-an ni. O ni loju ẹsẹ ti wọn raaye sa lọ mọ wọn lọwọ lawọn gba ọdọ Kabiyesi ilu naa lọ, lati lọ fiṣẹlẹ ọhun to wọn leti.
Ọba yii lo ni o waa ran awọn lọwọ to pe awọn ọlọpaa ti wọn si mu meji ninu awọn tọọgi naa, pẹlu ileri pe ọwọ yoo tẹ awọn yooku laipẹ yii. O waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Kabiyesi naa fun ifẹ to fihan si awọn, to si huwa gẹgẹ bi baba si wọn pẹlu.
No comments:
Post a Comment