Idunnu lo ṣubu layọ fun idile agba ọjẹ oniroyin fun amuludun, Arẹmu Adeniyi, tọpọ mọ si Arems, iyawo ẹ lo bimọ ọkunrin lanti lanti lonii, ọjọ Abamẹta Satide.
Ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita, lo ti dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o jẹ ki iyawo oun sọ kalẹ layọ ati alaafia. To si fi akoko naa kede faraye pe ọmọ tuntun ti darapọ mọ ẹbi naa, ti gbogbo wọn si fo fayọ.
O sọ pe ọpẹ nla lo jẹ fun ọkunrin ti iyawo ẹ ba bimọ layọ ati alaafia, nitori kinni naa ko rọrun, amọ ti Ọlọrun ko jẹ kawọn eeyan ba oun daro ibanujẹ, ti iya ati ọmọ naa si wa ni alaafia.
Arẹms sọ pe lakooko yii o, ọpẹ ṣaa ni, kawọn eeyan si maa ba oun dupẹ pẹlu.
No comments:
Post a Comment