Bi igbejo se bere ni pereu fun ti Ibo aare to kọja lo yii, Otunba Segun Sowumi, to je oludije dipo gomina ninu egbe oselu PDP, nipinle Ogun, ti gba awon adajo nimoran lati ma se ja awon eeyan nitanmo nitori awon ni ireti igbeyin tawon araalu nigbagbo ninu e.
Okunrin naa soro yii ninu leta to ko sawon adajo naa lati fi gba won lamoran.O so pe ninu erongba oun, gbogbo eru to wu wo lakooko Ibo yii ti wa lori awon igbimo ti won fee gbo ejo naa lo wa, awon lo si le so o di fifuye nipase eto idajo ododo.
Sowumi tun so pe, " A ni lati gbagbo pe eyin ni ireti opin fun gbogbo wa, e si ni lati mo pe ni ona kan si omii-in igbagbo wa lorileede yii ni pe ori yin ni eru wuwo wa, Bo tile je opo ti so igbagbo ninu lona kan si omii-in.
O safikun pe oun fee ki won mo pataki igbejo naa ni pe ki idajo ododo waye lori ibo naa ati pe ki won ma se sojusaaju ninu idajo ti won ba fee gbe kale.
Bee ni ki won si rii pe won fáwọn toro ba kan laaye lati rii pe won gbo ti enu won, ki won ma se je ki enikeni ko won laya je.
Segun Sowumi tun so pe," Loooto ni idajo Ile ejo lagbara,sugbon e gbodo je ko waye nilana ododo,ipinnu ti e ba gbe kale yoo ni ipa ati ase lorileede yii.
Bee naa lo so pe won gbodo fun ajo eleto idibo iyen INEC nipo lati tele Ilana ati ofin, ki won si je ki won mo awon ijakule ti won mu ba ise won.
No comments:
Post a Comment