Ọtunba Joel Ọlaniyi Ọyatoye, to jẹ aarẹ ẹgbẹ Aṣa Day lagbaaye ti sọ pe iwa ọmọ Yoruba to jẹ ọmọluabi lo maa n jẹ ki a di ẹni itẹwọgba kaakiri ibi gbogbo ta a ba de lorileede, nitori ibi teeyan ba de ni aṣa ẹ yoo ba a de.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba ẹgbẹ akọroyin ni ede Yoruba iyẹn iyẹn Proffessional Yoruba Media Association fọrọ jomitoro ọrọ ni alẹ ana. O ni gbogbo ibi ta a ba de ni wọn ti gbọdọ fẹ wa, nitori ojulowo iwa ọmọluabi ti wọn ri ninu wa.
O ṣalaye pe aṣa yii oun fẹẹ mọ si, idi niyi to fi jẹ pe titi di akoko yii loun ṣi n kẹkọọ ati pe awọn nnkan toto wa lawujọ wa lati jẹ ki a tubọ gbilẹ daadaa si ninu ẹ. Bẹẹ lo sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun bawọn aṣiwaju gan-an nilẹ Yoruba ko ṣe mu igbelarugẹ si ede ati aṣa wa.
O waa gba awọn oniroyin ede Yoruba ọhun nimọran pe awọn ni wọn le gba ara wọn kalẹ ti wọn ba fẹẹ jẹ ki aṣa ati ede Yoruba tubọ gbilẹ si nipa kiko ara wọn jọ lọọ sileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye lati fi ẹhọnu wọn han lori oju tawọn aṣiwaju wa ṣe n wo ede wa, ti wọn ko si bikita.
O ni ti wọn ba le ṣe eleyii, itiju nla ni yoo jẹ fawọn naa, nitori bawo ni ede abinibi ṣe le wa ku, ti wọn yoo si maa woo niran. Bẹẹ lo sọ pe ọpọ lo fẹẹ ba wọn ṣe, ti asọye ba si ti jọ wa, wọn yoo se ati pe nitori Ọlọrun ran oun lọwọ lo jẹ ki oun tete dide.
Bakan ni Ọyatoye tun mẹnuba ayajọ aṣa day ti ọdun yii, eyi to sọ pe orileede mẹta ni yoo ti waye, iyẹn lorileede Naijiria ninu oṣu kẹsan-an, London, ni ipari oṣu keje ati Canada ninu oṣu kẹsan-an, ohun to yoo si jẹ akori wọn fun ayajọ ọhun ni ‘’Ipa ti aṣa n ko ninu idagbasoke ọrọ aje’’ O ni ibẹ ni wọn yoo ti maa mu aṣa nikọọkan, eyi to le mu ọrọ aje wa.
O waa tan imọlẹ sii pe ọpọ eto toun ṣe lo jẹ pe owo ara oun loun maa n na lee lori, fun apẹẹrẹ eyi ti wọn ṣe ni Eko, o ni wọn ṣeleri fawọn pe gbogbo owo tawọn na, lawọn yoo da a pada amọ, to jẹ pe titi di akoko yii, awọn ko ri nnkankan.
Ọpọ lo si jẹ pe gbese loun maa jẹ lati fi ṣe aṣa day ọhun. Pupọ ninu awọn oṣere taọn ba gbe wa si Canada ni ki i san awọn, kaka bẹẹ owo ni wọn yoo tun maa le kaakiri, ati pe awọn kan ṣe nnakn wọnyii lati fi fun awọn eeyan ni oore ọfẹ iṣẹnmbaye iyẹn museun tawọn ni, ki wọn le wa maa wo awọn nnkan to wa nibẹ ati pe awọn ki i gba owo, ọfẹ ni.
O waa pari ọrọ ẹ lori afojusun ẹ lati ri i pe asa day da a duro lọjọ iwaju, to yoo le fa ajọ mii-in soke.
No comments:
Post a Comment