Eniola Sodiya, iyalode awon pedepede sayeye ojoobi lonii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 14 April 2023

Eniola Sodiya, iyalode awon pedepede sayeye ojoobi loniiInu ayo ati idunnu nla ni gbajumo ati ilu mo on ka sorosoro, to tun fi pipede yangan, Eniola Sodiya, to je iyalode awon pedepede wa a bayii nitori bi aseda se fi odun kun odun e lonii.

Gege bi iroyin to te wa lowo, oni ni ayeye ojoobi irawo obinrin naa,tawon oloolufe si ti ki i lati oru wa, ti won si ba a sajoyo naa

Opo awon eeyan lo si ti n fi adura ranse si eni to ti figba kan se eto, ka iroyin nileese redio Rock city, to wa niluu Abeokuta,lori ero ayelujara ibanidore e, ti won si n se adura fun un pe yoo se opo odun laye.

Eniola ti wa so pe oun fi ayajo ojoobi naa dupe lowo Olorun fun idasi e lori oun ati pe titi aye loun yoo maa gbe oruko re ga.

Bee lo tun ni dupe lowo gbogbo awon eeyan ti won ba sajoyo pelu adura pe oun rere ko ni tan loode onikaluku.


No comments:

Post a Comment

Pages