Ese o gbero lojo Aiku, Sannde, nigba ti gbajumo olorin emi, to tun je sorosoro nni, Hannah Babatunde, ti won pe ni HANNYFINGER, sayeye onibeta niluu Eko.
Ayeye ohun to waye ni soosi The Light Award and Salvation, to wa ni Ogundipe, Osoogun, Ketu ni obinrin naa ti sayeye ojoobi ogoji odun, bee lo tun fáwọn eeyan ni awoodu, bakan naa lo tun sefilole kaseeti tuntun to pe akole e ni Oluwakorede.
Lojo naa lawon olorin emi dabira pelu orin imisi olokan-o-jokan ti won fi n ba olojoobi naa sajoyo.
Lara awon to forin dabira lojo naa ni Dokita Rotimi Onimole topo awon eeyan mo si Oba Ara. Dare Praise, Eniola Praise atawon olorin emi mii-in.
Nigba to n ba oniroyin wa soro, Arabinrin Hannah Babatunde loun dupe lowo Olorun lori idasi e, to je ki oun je alaaye okan lati se ojoobi lonii.
Bee lo tun fi idunnu e bi awon eleyinju aanu se peju pese nibi ayeye onibeta to se naa. O waa gbadura pe nnkan ayo lo nii kuro nile onikaluku.
Wolii ijo naa to tun je oludasile, Wolii Okiki lo je olugbalejo pataki nibi ayeye naa.
No comments:
Post a Comment