Salvador fawọn ẹgbẹrun marun-un lẹbun ọdun lakooko awẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 9 April 2023

Salvador fawọn ẹgbẹrun marun-un lẹbun ọdun lakooko awẹGẹgẹ iṣe ẹ lọdọọdun, ti awẹ ba n lọ lọwọ, Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, tun ti ṣe bẹẹ lọdun yii nigba to fawọn araalu ti wọn to ẹgbẹrun marun-un lẹbun ọdun, nibi eto adura ati idanilẹkọọ to maa n ṣe.

Lọjọ Sannde, Aiku, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹrin, ni eto ọhun waye nile agba oṣelu ọhun to wa ni Salvador Tower, nibi ti awọn araalu paapaa julọ awọn musulumi ti kun wamuwamu, to si jẹ pe ibi ti wọn lọ ọhun ko fẹẹ gba awọn eeyan.

Ninu ọrọ ẹ nigba to n bawọn oniroyin, Salvador, sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun, to jẹ ki iru eto bẹẹ tun waye lonii. O sọ pe gbogbo wa la mọ pe nigba ti awẹ ba n lọ lọwọ, nnkan to ṣe pataki ni lati ṣaanu fawọn to ba ku diẹ kaato fun.

Ọkunrin naa sọ pe igba akọkọ ree, to oun ti maa n ṣe bẹẹ lakooko awẹ, o ni lara nnkan toun jogun ba lati ọdọ Baba oun ni, toun ko si kabamọ rara. Ati pe nnkan toun fẹran lati maa ṣe ni aanu paapaa julọ fawọn to ba ku diẹ kaato lawujọ.

Ọpọ awọn ti wọn janfani ẹbun awẹ naa ni wọn fi idunnu wọn han si Salvador, fun oore nla to ṣe fawọn, wọn tiẹ sọ bi ẹni pe ọkunrin naa ti ero ọkan wọn ni, nitori bawọn yoo ri aṣọ wọ fọdun tawọn yoo ra fọmọ lawọn n ro laimọ pe Ọlọrun yoo lo agba oloṣelu naa fawọn.

Adura ti wọn ṣa n ṣe ni pe Ọlọrun ko nii gba aṣọ aṣiiri lara ẹ. Ko to to akoko naa ni idanilẹkọọ ti kọkọ waye lori pataki awẹ tawọn eeyan naa n gba ati ọna lati  ma sin Ọlọrun lọna totọ ati eyi to yẹ.

 

No comments:

Post a Comment

Pages