Ẹgbẹ oṣelu Labour ipinlẹ Eko da Kayọde Salako , Salvador atawọn mẹrin-in mi duro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 6 April 2023

Ẹgbẹ oṣelu Labour ipinlẹ Eko da Kayọde Salako , Salvador atawọn mẹrin-in mi duro


Ṣe lọrọ tun gbọna mii-in yọ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour tipinlẹ Eko, lonii, nigba ti wọn kede pe awọn ti da awọn ọmọ ẹgbẹ wọn mẹfa duro lori iwa agabagebe ati ṣokeṣodo ti wọn ni wọn ṣe lakooko ti ibo waye.

Nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe lọsan yii, ni Ọgbẹni Sam Okpala, to jẹ akọwe ẹgbẹ ọhun ti sọ lorukọ alaga ẹgbẹ wọn iyẹn Arabinrin Dayọ Ekong, lo ti ṣalaye pe awọn gbe igbesẹ ọhun lẹyin tawọn igbimọ ti wọn yan lati ṣe iwadii lori awọn eeyan ọhun fi abọ jẹ wọn.

Awọn ti da duro naa ni Kọmureedi Olukayọde Salakọ, to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ọnarebu Moshood Salvador,Kọmureedi Olumide Adesoyin, Kọmureedi Ọpẹyẹmi Taiwo,Ọnarebu Mutiu Okunlọla,ati Kọmureedi Theodore Enzoma.

Akọwe ẹgbẹ naa tun sọ pe awọn ṣakiyesi nnkan to waye lakooko ibo to kọja naa pe awọn kan ti wọn pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ  ni wọn ṣiṣẹ tako wọn, ti wọn si n ṣiṣẹ fawọn ẹgbẹ alatako. Nitori eyi lawọn ṣe gbe igbimọ kan dide, eyi ti igbakeji alaga ẹgbẹ naa jẹ alaga ẹ.

Gẹgẹ bi awọn ṣe jẹ ẹni ti ki i gbe ẹlẹbi fun alare, idi niyi tawọn fi fawọn tọrọ naa kan laaye lati wa sọ tẹnu wọn. O sọ pe bo tilẹ jẹ pe meje ni wọn,ṣugbọn ọkan ninu wọn ti sọ gbangba pe oun ki i sọmọ ẹgbẹ wọn mọ, nitori ẹ lawọn ko ṣe ba a janpata, to si jẹ pe awọn mẹfa yooku lawọn doju ẹsun naa kọ.

Sam sọ pe awọn ko nii gba kawọn kan maa pe ara wọm lọmọ ẹgbẹ Labour, ki wọn si tun maa ṣiṣẹ fawọn alatako, o ni ko si nnkan to jọ bẹẹ rara.

Bakan naa lo tun sọ pe awọn nigbagbọ ninu alaga ẹgbẹ naa lapapa iyẹn Agbẹjọro Julius Abure atawọn igbimọ yooku mẹrin yooku ti ile ẹjọ giga kan niluu Abuja, sọ pe ki wọn ye pe ara wọn alaga ni oloye ẹgbẹ naa mọ.

O sọ pe idajọ ile ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ nitori alaga ẹgbẹ naa ti ṣiṣẹ takuntakun latigba to ti depo naa, eyi to si ṣe tọka si. O ni awọn ọta ti wọn ko fẹẹ ki ẹgbẹ naa gbero lo wa nidi ọrọ naa ati pe ile ẹjọ mii-in to wa ni Benin, ti tako igbẹjọ naa, nibi ti wọn ti sọ pe ko sẹni to lagbara lati yọ awọn oloye ẹgbẹ lapapọ nipo.

 


No comments:

Post a Comment

Pages