Lati ana ti Ogagun Oladipo Diya ti jade laye lawon eeyan jakanjakan ti n ranse ibanikedun sawon molebi oloogbe naa.
Lara won ni atona ile Yoruba,Oloye Bode George, eni to tun figba kan sise labe Diya, nigba toun naa wa lenu ise oloogun.
O sapejuwe iku Ogagun Diya, gege bi eni to ti pari ije e lode aye, to si fi iyooku sile lati di ohun itan.
Agba oselu ninu egbe PDP, ni Eko, tun so pe Olorun lo fun wa, nigba to ya lo si gba nnkan e lo.
Bode George tun so pe,"Oluwa wa lo fun wa, o si ti mu nnkan e pada lo,Ki Olorun ba wa fun nisinmi ayeraye ati pe ki ipapoda e je ibukun fun ebi ati ore"
" O ti se iwon to le se nile aye e je ka fi iyooku sile, to ti di oun itan. O daaro, titi di aaro ojo idajo. Ki awon Angeli maa korin fun isinmi yin"".
Bee lo tun bawon ebi kedun pupo paapaa julo Simi.
No comments:
Post a Comment