Ẹ ẹ wa gbọ o! PDP Ogun fẹẹ lo apapọ ẹgbẹ oṣelu lati parọ faraalu. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 25 March 2023

Ẹ ẹ wa gbọ o! PDP Ogun fẹẹ lo apapọ ẹgbẹ oṣelu lati parọ faraalu. 

Ẹgbẹ kan ti wọn pe ni  Concerned citizens, nipinlẹ Ogun, ti pariwo sita lọsẹ to kọja lori bi wọn ṣe ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Ladi Adebutu, ṣe n gbidanwo lati ra awọn ẹgbẹ oṣelu mii-in.

 

Iwadii fi ye wa pe Adebutu, to lulẹ ninu ibo gomina lọjọ Satide, to kọja yii, ni wọn lo fẹẹ pe ipade oniroyin nibi ti wọn ti fẹẹ lo ẹgbẹ apapọ oṣelu tipinlẹ Ogun, iyẹn Inter-Party Advisory Council (IPAC) pẹlu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu ti wọn forukọ silẹ,pẹlu ileri miliọnu meji naira ẹnikọọkan wọn.

 

Ipade oniroyin ọhun ni wọn sọ pe yoo waye Park Inn. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti sọ igba ti yoo waye sibẹ, wọn n gbero ẹ lọwọ.

 

Ẹnikan to sunmọ wọn to ju ọrọ naa sita sọ pe’’ Ladi atawọn ẹgbẹ ẹ mọ pe awọn ko le jawe olubori ni kootu ti wọn n gba lọ, nitori ti wọn lọ sọ awọn nnkan ti ko ri bẹẹ ninu ofin idibpo tọdun 2022, nitori ẹ lo ni wọn se gbidanwo lati maa sọ isọkusọ fawọn araalu, ti wọn si mọ pe wọn ko le jẹ bọ.


No comments:

Post a Comment

Pages