Ẹ fi ti Anọbi Mohammadu ṣe apẹrẹ rere lakooko awẹ yii- Saidi Oṣupa - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 24 March 2023

Ẹ fi ti Anọbi Mohammadu ṣe apẹrẹ rere lakooko awẹ yii- Saidi OṣupaIrawọ olorin fuji nni, Dokita Saidi Oṣupa, ti rọ gbogbo awọn musulumi lati fi ti Anọbi Mohammed, ṣapẹẹrẹ rere lakooko awẹ Ramadan ti wọn wa, ki wọn si sa fawọn nnkan ti ko ni jẹ ki awọ ti wọn n gba naa ṣe itẹwọgba.

Ọba orin fuji sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita lati fi ki awọn musulumi ododo fun ti awẹ to n lọ lọwọ ọhun. O sọ pe  gẹgẹ bi awọn ṣe mọ Anọbi, iru akoko bayii, ṣe lo maa n dide iranlọwọ sawọn ti ko ni, bẹẹ lo ni o yẹ kawọn to n tẹle naa maa ṣe lakooko yii.

Saidi Oṣupa tun ṣalaye siwaju pe pataki awẹ tawọn musulumi n gba lo wa fun iranti, gẹgẹ bi oṣu mimọ, eyi to jẹ ọkan lara igbesẹ ti Anọbi Muhammad gbe nigba to wa laye.

Bẹẹ  ni ọkunrin ti wọn tun pe ni Olufimọ, tun rọ awọn musulumi ati gbogbo ọmọ orileede yii lati ri pe wọn ran tọkunrin-tobinrin to ku diẹ kaato fun lawujọ, ki awọn le ri ọwọ lọ sẹnu lakooko yii.

O waa gbadura pe ki Allah ko ṣetẹwọgba gbogbo awẹ ati adura akoko Ramadan naa, ki wọn si ni okun ati agbara ti wọn yoo fi le gba a ja.


No comments:

Post a Comment

Pages