Wolii Isreal Ọladele Ogundipẹ, ti ijọ Genesis Global, ti rọ awọn musulumi lati lo awẹ Ramadan to n lọ lọwọ yii lati fi gbadura fun isọkan laarin awọn ọmọ orileede yii, ki wọn ma ṣe jẹ ki awọn naa lọ lasan.
Ojiṣẹ Ọlọrun rawọ ẹbẹ naa ninu atẹjade to fi sita, to fi ki awọn musulumi ku awẹ ọgbọn ọjọ ti wọn wa lẹnu ẹ bayii. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni awẹ ti wọn n gba naa ki i ṣe lati fi ebi pa inu tabi fi oungbẹ gbẹ ara wọn lasan, bi ko ṣe lati lo anfaani naa lati fi tọrọ fun idariji, ki wọn si sunmọ Ọlọrun.
O waa rọ awọn aṣiwaju ẹsin islam ati gbogbo musulumi lapapọ lati jẹ ki igbagbọ wọn rọ mọ oṣu mimọ ti wọn wa yii, ki wọn si gbadura fun ifẹ paapaa bi eto idibo gbogbogboo ṣe ṣẹṣẹ pari yii, lati jẹ ohun gbogbo wa ni isọkan lori bi idagbasoke yoo ṣe de ba orileede yii.
No comments:
Post a Comment