Pẹlu bi awẹ Ramadan, ṣe n lọ lọwọ, gbajumọ olorin fuji nni, Alaaji Abass Akande Obesere, ti gbe kasẹẹti tuntun jade lakooko awẹ yii, eyi to pe akọle ẹ ni ‘’ Mo Tẹwọ Adura’’
Gẹgẹ bi atẹjade ti oluranlọwọ nipa iroyin ẹ, Ọgbẹni Wasiu Arẹmu, tọpọ mọ si Arẹms, fi sita lo ti sọ pe gbogbo eto lo ti pari fun kasẹẹti ọhun, eti to ni ko ni pẹ wa lori igba.
O sọ pe kasẹẹti ọhun lo ṣe rege pẹlu awẹ to wa nita yii, eyi to ni awọn adura ti ko ṣe fojudi wa nibẹ. Bẹẹ lo tun sọ pe Obesere lo akoko naa lati fi ki awọn musulumi ododo ku ti awẹ to wa nita yii.
O ni ki wọn lo awẹ naa lati fi tẹsiwaju, ki wọn si fi bẹbẹ adura fun isọkan, igbega ati aṣeyọri fun orileede yii bẹẹ lo ni oun nireti pe awọn aṣiwaju ẹsin islam yoo lo oṣu naa lati fi gbadura fun isọkan Naijiria.
No comments:
Post a Comment