Gbajumọ olorin fuji nni, to tun jẹ Agbaakin Abọbagunwa ilẹ Yoruba, Alaaji Abass Akande Obesere, ti sọ pe bi Gomina Ṣeyi Makinde, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, ṣe wọle gomina lẹẹkeji, oriire nla lo jẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa.
Ọga onifuji naa sọrọ ọhun ninu atẹjade kan to fi sita, eyi to fi ki Gomina Makinde, ku oriire lori bawọn araalu ṣe dibo yan –an lẹẹkeji, ninu ibo to waye laipẹ yii. O sọ pe awọn iṣẹ akikanju ti ọkunrin naa ṣe ni saa akọkọ tun jẹ ọkan lara awọn nnkan to ran lọwọ to fi wọle.
O ṣapejuwe Makinde gẹgẹ bi aṣaaju, to ni ipinnu rere lọkan fawọn to n ṣejọba le lori, o ni awọn nnakn wọnyii ni awọn araalu ro mọ lara ti wọn fi sọ pe ko maa ba iṣẹ ẹ lọ. O waa rọ ọ lati tẹsiwaju nipa bi ọrọ aje ipinlẹ Ọyọ yoo ṣe tubọ dagbasoke ninu iṣsjọba ẹlẹẹkeji ẹ.
Bakan naa lo tun rọ awọn araalu lati fimọ sọkan pẹlu irẹpọ pẹlu lati le ṣaṣeyọri ninu ijọba ẹleekeki Gomina, Omi tuntun naa.
No comments:
Post a Comment