Gbajumọ onifuji nni, to tun jẹ Ọba orin, Dokita Saheed Akorede Oṣupa, ti ṣapejuwe ìpadabọ Ṣeyi Makinde, ti ẹgbẹ oṣelu, PDP, to wọle fun gomina lẹẹkeji nipinlẹ Ọyọ, gẹgẹ bi awọn iṣẹ rere to fi mu idagbasoke ba awọn araalu nigba akọkọ to fi wa nipo ọhun.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita, nipasẹ oluranlọwọ iroyin ẹ, Ọgbẹni Wasiu Arẹmu, lo ti ba Gomina tawọn eeyan tun pe ni omi tuntun naa yọ fun bi wọn ṣe dibo yan-an wọle, ninu ibo gomina ti wọn di kọja naa.
Saidi Oṣupa tun fikun ọrọ ẹ pe ohun iwuri lo jẹ fun Gomina Ṣeyi Makinde fawọn iṣẹ akanṣe ti wọn le ri tọka si to ṣe, o ni awọn eleyii gan-an ti to lọtọ. O ni bo tilẹ jẹ pe oju ogun le lakooko ipolongo ṣugbọn oun dupẹ pe Ọlọrun muu bori.
O waa gbadura fun Gomina ipinlẹ Ọyọ naa pe ki Ọlọrun tubọ fun un ni ẹmi ti yoo fi dari ijọba lẹẹkeji yii, ki awọn araalu le tubọ jẹ anfaani ijọba dẹmokireesi to wa nita.
No comments:
Post a Comment