Ọlọrun lo yan Dapọ Abiọdun lati ṣe gomina lẹẹkeji- Wolii Ogundipẹ Gẹnẹsis - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 24 March 2023

Ọlọrun lo yan Dapọ Abiọdun lati ṣe gomina lẹẹkeji- Wolii Ogundipẹ Gẹnẹsis

Ojiṣẹ Ọlọrun nni, Wolii Isreal Ọladele Ogundipẹ, tọpọ mọ si Gẹnẹsis, ti sọ pe  ipadabọ Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogun, jẹ nnkan ti Ọlọrun mọ si, to si yan an lati wa dari ipinlẹ naa lẹẹkan si.

Ninu iṣẹ ikini ku oriire ti ojiṣẹ Ọlọrun naa fi ranṣẹ nipasẹ akọwe iroyin ẹ, Ọgbẹni Wasiu Aremu, tọpọ mọ si Arẹms, to nileeṣẹ 1steleven9jatv, lo ti ba Gomina naa yọ fun aṣeyọri nla to ṣe ninu ibo ti wọn di lọsẹ to kọja yii.

Wolii Gẹnẹsisi tun sọ pe bi Dapọ Abiọdun tun ṣe pada lẹẹkeji yii yoo jẹ anfaani nla fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, nipasẹ isakoso rere ati lati mu ileri to ṣe lakooko ipolongo ṣẹ. Bẹẹ lo tun gboriyin fawọn araalu lori bi wọn ṣe jade lọpọ yanturu dibo, eyi to ni o tumọ si pe wọn nifẹẹ si ijọba tiwa-n-tiwa.


No comments:

Post a Comment

Pages