Ibo Aarẹ: QueenSeidat Almubarak Awa kí Aṣíwájú Bọ́lá Tinubu àti Sanwo-Olu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 24 March 2023

Ibo Aarẹ: QueenSeidat Almubarak Awa kí Aṣíwájú Bọ́lá Tinubu àti Sanwo-Olu


Ọkan gboogi ninu awọn obinrin ti wọn jẹ ojiṣẹ Ọlọrun, ti wọn si tun gbe iṣẹ Ọlọrun dani, ti wọn si tun jẹ ọmọ ẹni Ọlọrun ni QueenSeidat Almubarak Awa. Obinrin onimọ nla naa to fi orileede Amẹrika ṣebugbe ti ranṣẹ ikinni ku oriire si aarẹ ti a ṣẹṣẹ dibo yan lorileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ati gomina ti wọn sẹsẹ dibo fun nipinlẹ Eko, Babajide Olusọla Sanwo-Olu.

Lasiko to n ba oniroyin wa sọrọ,  QueenSeidat  ´Ni a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o gba adura awọn ẹni Ọlọrun lori ọrọ Aṣiwaju Tinubu, ṣaaju ka to o dibo ni awọn ẹni Ọlọrun ti wọle adura fun Aṣiwaju, a si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o gba adura wa.  Ṣe ẹ ranti pe mo sọ fun yin nigba kan pe lagbara Ọlọrun, Tinubu lawọn eeyan yoo fibo gbe wọle, Ọlọrun si ti gba adura wa bayii’.

‘Mo nigbagbọ pe Aṣiwaju yoo mu igbe aye to rọrun ba gbogbo ọmọ orileede yii nitori pe wọn nifẹẹ orileede yii denudenu, irọrun gbogbo wa lo si jẹ wọn logun, gbogbo awọn eeyan to n gbe niluu Eko ni wọn ri awọn idagbasoke ọlọkanojọkan ti Aṣiwaju mu ba ipinlẹ Eko nigba ti wọn wa nipo gomina.

Bẹẹ ni mo tun fẹẹ rọ gbogbo awọn eeyan ti wọn yoo ṣiṣẹ papọ Asiwaju lati ṣe daadaa gẹgẹ bi Aṣiwaju se n gba lero, ṣe ẹ mọ pe igi kan ko le da igbo ṣe.

Onimọ nla ninu ẹsin musulumi yii tun ki igbakeji gomina Eko, Dokita Kadri Hamzat naa ku oriire, ko s a i ki iyawo aarẹ tuntun naa, Senatọ Olurẹmi ku oriire ipo ti Ọlọrun gbe awọn ati ọkọ wọn si yii, bẹẹ lo gba a ladura pe asiko wọn yoo tu gbogbo awọn ọmọ orileede yii lara. 


No comments:

Post a Comment

Pages