Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC, ninu ibo to waye lana-an, ti so pe awon yoo je kawon araalu mo igbese ti yoo gbe lori ibo to waye naa.
Ninu atejade to fowo si losan yii lo ti koko dupe lowo awon eeyan ipinle Ogun fun atileyin won lori bi won se jade dibo lana- an.
O gboriyin fáwọn eeyan ipinle naa lori ipinnu won lati le ijoba to wa lode yii kuro nitori iriri ti won ni lori isakoso won lati bi odun merin seyin.
Bee ni oludije yii tun fi emi imoore han si awon agba egbe, to fi mo awon asoju lokunrin ati lobinrin fun bi won se fi tokantokan duro ti won lati le je ki ipinle naa lo si oke.
Otegbeye salaye siwaju pe, "Pelu gbogbo agbara ati erongba wa, sibe won si ta Ibo, won se awon eeyan nijamba, ti won si tun da opo ibudo idibo ru, nitori lati ma se je ki isakoso rere waye"
O ni ise ti n lo lowo lori igbese ti won yoo gbe leyin tawon ba fi oro lo awon to je agba egbe, tawon yoo si je kawon araalu mo laipe.
O no sibe naa, oun ro won lati ma se rewesi nipa erongba won kaka bee ki won si maa dupe lowo Olorun fun anfaani to fun won.
No comments:
Post a Comment