Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ti ẹgbẹ oṣelu People Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ogun ti sọ pe ohun pataki to le mu ki ajọ to n ṣeto ibo lorileede yii, iyẹn INEC, ṣe aṣeyọri lori ibo gomina ti wọn di lonii, ni ki wọn ṣa ipa wọn lati rii pe wọn ṣeto esi ọhun bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ nigba to n dibo ni wọọdu ẹ niluu Abẹokuta. O sọ pe loootọ ni ibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ti wọn di naa lọ ni alaafia, ti wọn ti si n tẹle awọn igbesẹ to yẹ fawọn olukopa to wa dibo naa.
O ni nnkan to le mu ijakulẹ ba aṣeyọri ti ajọ INEC n ṣe yii ni ti wọn ba kuna lori awọn igbesẹ to yẹ fun ibo to n lọ naa. O ni idaniloju wa pe ẹgbẹ oṣelu PDP, ni yoo jawe olubori ninu ibo naa lẹyin opin ohun gbogbo.
Ṣẹgun Ṣowumi toun naa dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, ninu ibo abẹle ọhun tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn eeyan jade sita lakooko yii ti wọn wa dibo, ohun kan tawọn duro de tawọn si nireti ni pe gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ṣe pariwo ẹ pe wọn yoo fi esi ibo ọhun ransẹ taara si pọta Abuja.
O ni, “ Nnkan ti mo fẹ ki ẹ mọ ni pe tawọn eeyan ba jade dibo gẹgẹ bi ojuṣe wọn lawọn ẹka ti wọn la silẹ fun wọn, awọn eeyan a fẹẹ mọ bo ṣe lọ. Pẹlu nnkan ti emi si ri yii o, ẹrọ BVAS, ṣiṣẹ to yẹ lati yẹ awọn oludibo wo.
O tẹsiwaju pe, “Ni bayii, awa ti ṣe ti wa, ẹ jẹ kawọn to wa nidii lati ka a naa ṣe ti wọn, ki awọn ti wọn yoo si fi ranṣẹ naa ṣe ti wọn pẹlu, ki awa fi gbogbo yooku le Ọlọrun lọwọ.
No comments:
Post a Comment