Oludije fun ipo gomina labe egbe oselu ADC, Agbejoro Biyi Otegbeye, ti gboriyin lori bi eto idibo gomina to n waye naa se n lo irowo-rose
Oludije naa soro yii lakooko to n dibo ni woodu e to wa ni State hospital, Ilaro, Ward 1, Unit 1, nijoba ibile Egbado South nipinle Ogun.
O so pe idibo to n lo lowo naa yato si ti aare to koko waye. O ni pelu ogo Olorun, gbogbo nnkan lo bo se to ati bo se ye, tawon eeyan si n tu yeye jade.
Otegbeye so pe, Pelu nnkan ti mo foju mi ri, Ibo yii yato gedegbe si ti aare ta a di kį»ja. Loooto lawon eeyan ko ti ma jade bo se ye sugbon mo nigbagbo pe won si n bo wa.
O so pe gbogbo eeyan lo ni oore ofe lati wa dibo, ki won si duro ti Ibo won, awon lo fe nnkan to le da wahala sile nitori orisi iroyin lawon ti gbo ni ana.
Amo o da oun loju pe awon alaabo ilu ti n sise won lati rii pe abo wa fun emi ati Ibo awon eeyan.
O wa so pelu idaniloju pe oun ni yoo gbegba oroke ninu Ibo naa, ati pe egbe oselu ADC ni yoo gba akoso
No comments:
Post a Comment