Isejoba ipinle Ogun: Idi ti Eleyii fi gbodo lo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 17 March 2023

Isejoba ipinle Ogun: Idi ti Eleyii fi gbodo lo
Opo awon olugbe to fi mo elegbejegbe ni won ti n so pe dandan ijoba to wa lode yii nipinle Ogun, ko gbodo pada wole ninu Ibo ti yoo waye ni Satide ose yii.

Gege bi ipade oniroyin tawon elegbejegbe kan ninu eyi tawon lanloodu, onisowo ati ileese kan to n je  Key Professional, se ni won ti so o di mimo pe gbogbo ona lawon yoo gba lati ri pe Gomina Dapo Abiodun ko gba wole, ninu egbe ibo gomina yii.

Ninu oro Ogbeni Kehinde Ibukunola to je alaga agbegbe naa so pe o se je pe igba ti ibo n bo lona ni Gomina sese wa n se awon nnkan to ye ki ti se fáwọn araalu ripe.

Fun apeere lati nnkan bi odun merin seyin lawon to m pariwo nipa ipo ti ona
 ti  Elega/Mokola wa, ti ko  bawon wa nnkan se si titi di akoko yii.

Bee ni won tun so pe edun okan lo je fáwọn pe opo ise akanse ti ijoba ana fi sile ni Gomina Abiodun pati ti ko ya si rara, ti ko si bojumu.

" Gomina ko ileese panapana laisi awon ohun elo bii Moto ti won yoo maa lo fi sise, ki lo de to fi je pe aawo yelo ni won fi kun un ti won ko lo eyi to je ti igbalode to je atewogba"


Bee ni won tun so pe  Dapo Abiodun ko ri atunse si oro awon osise feyinti ati osise ijoba kaka bee se ni won lo fun mi egberun marun un Naira, se owo Ibo ni ki won pe mi abi ewo?

 Won ni ki lo de to fi je laaarin odun merin ti Gomina ko fi sabewo sawon ileese iroyin to je tipinle Ogun bii OGTV, OGBC, PRINTING CORP lati nnkan bi odun merin to ti wa lori aleefa. Kaka lo se bee awon tita lo yan laayo lati maa lo.

Ni bayii, pelu awon ikuna ti won no Dapo Abiodun ti mu ba ijoba nnkan to ku fun un ni pe ko maa di eru e sile, ko maa lo sile, nitori ko kun oju osuwon to lati sakoso ipinle Ogun.No comments:

Post a Comment

Pages