Ibo Gomina;Jandor ko lenu nibe Gbadebo ni PDP yoo dibo gomina fun- Bode George - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 16 March 2023

Ibo Gomina;Jandor ko lenu nibe Gbadebo ni PDP yoo dibo gomina fun- Bode GeorgeSe loro tun foju han ninu egbe oselu PDP, nipinle Eko nigba ti won so pe Ibo gomina ti yoo waye lojo Satide, yii Gbadebo Rhodes-Vivour tinu egbe oselu Labour lawon yoo dibo fun.

Nibi ipade oniroyin to waye lonii ni Oloye Bode George, to je Atona Ile Yoruba,ati alaga egbe tuntun ti won sese da sile ti won pe no Omo- Eko Pataki, ti se ni alaye pe Labour lawon  yoo fun ni Ibo gomina won ki i se Jandor, to je oludije won.

Bakan naa ni Oloye Bode George tun  lo akoko naa lati fi ke gbajare si gbogbo omo ipinle Eko lati wa ni isokan, ki won fi le gba ara won kale lowo ijoba to wa lode yii.

O so pe akoko ti to lati fi eto oselu to n lo lode yii ranti Onimo-Ero Funso Williams, o ni iku e ko gbodo lo lasan.

 Nitori idi eyi, egbe kan ti won sese da sile ti won pe ni Omo- Eko Pataki je eyi to nii se ki Ibo to n bo lona ohun waye irorun laisi wahala kankan.

Bee lo ro ajo eleto idibo lati je Ibo naa waye ni ona to se itewogba o waa mu ayolo oro kan jade ninu eyi ti Aare orileede igba kan, Abraham Lincoln, ti so pe ipinle wa yii gbodo wa labe Olorun, to ni ominira, ti yoo je ijoba awon eeyan, ijoba tawon eeyan ni ati eyi tawon ijoba fáwọn eeyan ti lo si ni segbe.

Bakan lo ni gbogbo awon omoota ti won le da wahala sile  lo ye kawon alaabo ilu ti mu, ki won si ri pe abo to daju wa fun emi ati dukia awon araalu.


No comments:

Post a Comment

Pages