Salvador pada leyin Gbadebo,Sanwo-Olu lo ba lo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 16 March 2023

Salvador pada leyin Gbadebo,Sanwo-Olu lo ba loBo tile je pe ko ju wakati mejidinlaadota lo mo ti Ibo gomina yoo waye lawon APA ibikan lorileede yii, orisirisi awon ayipada lo ti n de laarin awon egbe oselu.

Lara e ni bi Onarebu Moshood Salvador, to je oludije seneto labe egbe oselu Labour ninu Ibo to kọja se kede pe Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinle Eko, loun atawon omo leyin oun yoo dibo fun gege bi gomina ninu Ibo ti yoo waye lojo Satide, ose yii.

O soro naa nibi ipade oniroyin to waye lonii, o so pe ka mu ti oro oselu kuro, Gomina Sanwo-Olu lo koju osuwon ju ninu gbogbo awon oludije to jade dupo naa pelu awon ise nla to ti se seyin.

Salvador so pe wiwole eleekeji e yoo tubo mu idagbasoke ba ipinle Eko. O so pe ninu bi a ba soro nipa iriri, Sanwo-Olu ni iriri ju Gbadebo to dupo gomina labe egbe oselu Labour lo.

Bee lo je ko di mimo pe igbese toun gbe yii ki i se pe oun lo darapo mo APC gege bi aheso tawon kan n so kaakiri. Sugbon oun ko le sise fun Gbadebo nitori gbogbo igba toun naa fi polongo ibo to kọja yii ko se atileyin kankan foun kaka bee oludije PDP lo so pe o sise fun.

Bakan naa lo ni Peter Obi to dije fun ipo aare labe Labour ti so fáwọn pe kawon ma dibo nitori egbe bi ko se iwa ati iriri, eyi toun mo pe Sanwo-Olu ni ju Gbadebo lo.

Ninu oro Obafemi Hamzat, igbakeji Gomina ipinle Eko to wa nibe, o gboriyin fun igbese ti Salvador atawon eeyan e gbe pelu ileri pe awon ko nii ja won nitanmo.

Bee lo tun ti awon odo lati maa sa ipa won lori bi idagbasoke yoo se de ba ilu, ki won ma se maa te eti si gboyi soyi.

No comments:

Post a Comment

Pages